Ààrẹ Tinubu pàṣẹ mímú àdínkù 60% bá iye owó tí wọn ń ná tẹlé káàkiri ìrìnàjò

Aworan aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Aarẹ Naijiria Bola Ahmed Tinubu ti mu adinku ba iye owo irinajo fawọn to n tẹle kaakiri.

Ajuri Ngelale agbẹnusọ aarẹ lo fidi ọrọ yi mulẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nile ijọba Aso Rock lọjọ Iṣẹgun.

Gẹgẹ bo ṣe wi, eyi jẹ ọna kan ti ijọba yoo fi mu adinku ba iye owo ina lori lilọ bibọ aarẹ.

O tẹsiwaju pe igbesẹ yi yoo kan iye awọn ti yoo maa kọwọrin pẹlu aarẹ, igbakeji aarẹ, iyawo aarẹ awọn minisita to fi mọ adari ileeṣẹ ijọba.

O ni "Aṣẹ yi aarẹ Tinubu pa kii ṣe nkan tàwọn eeyan le ṣe to ba wu wọn."

Afojusun iye ti igbesẹ yi yoo wa nisiro adinku yoo sunmọ ida ọgọta ninu ida ọgọrun gẹgẹ bi Ngelale ṣe sọ.

O ni bayii awọn ti yoo ba aṣẹ rinrin ajọ jade lọ si orileede mi ko ni ju ogun lọ.

Bakan naa ni Aarẹ sọ pe awọn minisita ko lanfaani lati mu ju eeyan mẹrin tẹle wọn ti wọn ba n lọ irinajo ilẹ okere.

Ni tàwọn olori ileeṣẹ ìjọba amugbalẹgbẹ ko gbọdọ ju meji ti yoo tẹle wọn lọ irinajo ilẹ okere.

Ko yọ awọn ẹsọ alaabo naa silẹ.

Ngelale sọ pe aarẹ ko ni ko awọn ẹsọ alaabo pupọ lẹyin to ba n ṣe irinajo lọ si awọn ipinlẹ Naijiria.

Gẹgẹ bo ṣe salaye ti aarẹ ba fẹ lọ si ipinlẹ kan, awọn ẹsọ ipinlẹ naa ni yoo pese aabo fun.

Ọrọ yi kan igbakeji aarẹ ati awọn oṣiṣẹ ijọba mii.

Ko daju ohun to mu iyipada yi waye amọ o ti pẹ ti awọn ọmọ Naijiria ti n tẹnu mọ pe iye owo ti ilu n na lori awọn adari ilu ti pọju.

Bẹrẹ lati ori aarẹ to fi mọ awọn mii ni ẹka ijọba bi ẹka aṣofin iye owo ti Naijiria n na lori awọn to wa ṣiṣẹ sin ilu wa lara eyi to pọju lagbaye.

Bọ ṣe baalu aarẹ ni to fi mọ ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn fi n gbe aarẹ kaakiri owo tabua ni Naijiria n na lojumọ lati fi gbọ bukata awọn ti araalu yan si ipo.