Ọwọ́ tẹ afurasí ọ̀daràn l'Ondo lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tó jáde l'ẹ́wọ̀n

afurasi

Ọdọmọkunrin kan, Matthew Simeon, ọmọ ọdun mọkanlelogun, ni ọwọ awọn amọtẹkun ti tẹ nipinlẹ Ondo fun iwa ọdaran lẹyin ọjọ mẹrin to jade lẹwọn.

Simeon, ọmọ bibi ilu Abakaliki, lo jade lẹwọn lọjọ kini, oṣu kini, ọdun 2024 lẹyin ọdun kan to lo fun jijẹbi ẹsun ole ati tita oogun oloro.

Ninu ọrọ rẹ, Simeon wi pe nibi ti oun ti fẹẹ ta waya ina ti oun ji ni wọn ti mu ohun.

“Ọjọ kini, oṣu kini ni mo jade lẹwọn, ti wọn si tun pada mu mi lọjọ kẹrin, oṣu kini nibi ti mo ti fẹẹ ta ẹru ti mo ji.”

Nigba to n foju ọdaran naa atawọn mejidinlọgbọn miran lede nilu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo, adari Ikọ amọtẹkun nipinlẹ naa, Akogun Adetunji Adeleye, wipe afurasi ni wọn ti mu bii igba mẹta to si ṣẹẹ dari ẹwọn loṣu yii.

afurasi

Adetunji wi pe “o ya wa lẹnu pe ẹni to de lati ẹwọn lẹyin ọdun kan tun le pada sidi iwa ọdaran lẹyin ọjọ mẹta.

“Ẹsun ole jija ati tita egbogi oloro ni wọn fi ran an lẹwọn ọdun kan, to si tun pada sidi iwa ọdaran naa lai tii pe ọsẹ kan to jade.”

Adetunji wi pe gbogb awọn to ba fẹẹ hu iwa ọdaran nipinlẹ naa ni ko nii si aaye fun nitori pe abo to peye yoo wa jakejado ipinlẹ naa.

Lara awọn ti wọn fi oju wọn lede ni awọn afurasi adigunjale, ajinigbe, ati ọkunrin kan to lawọn ibọn agbelẹrọ lọna aitọ.