Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ nípa eégún Zangheto tó ní í ṣe pẹ̀lú ìran Yorùbá ní orílẹ̀ èdè Benin?

Àkọlé fídíò,
Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ nípa eégún Zangheto tó ní í ṣe pẹ̀lú ìran Yorùbá ní orílẹ̀ èdè Benin?

Gbígbé àṣà àti ìṣe ẹ̀yà tàbí ìran kan máa ń jẹ́ ohun ìwúrí fún àwọn ìran bẹ́ẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ ní ọ̀rọ̀ rí fún àwọn ẹ̀yà Yorùbá tó wà ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Benin bí wọ́n ṣe ṣayẹyẹ ọdún “Vodun Days” fún ìgbà àkọ́kọ́.

Ìlú Ouidah ni ayẹyẹ ọdún náà ti wáyé.

Pàtàkì ọdún náà ni gbígbé àwọn òrìṣà, àṣà àti ìṣe ilẹ̀ Yorùbá lárugẹ.

Níbi àyẹyẹ náà ni àwọn eégún oríṣiríṣi ti dárà, tí wọ́n sì ń pe ẹ̀sà lọ́kan-ò-jòkan láti fi dá àwọn àlejò lárayá.

Káàkiri àgbàyé ni àwọn ènìyàn ti lọ sí orílẹ̀ èdè Benin láti kópa nínú ayẹyẹ náà.

Lára àwọn eégún tó dára níbi ayẹyẹ náà ni eégún Zanghetọ.

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Benin, Patrice Talon náà báwọn péjú pẹ́sẹ̀ síbi ayẹyẹ náà.

Àkọlé fídíò, Ọdún Zangheto jẹ́ eyi ti wọ́n fi n gbe aṣa àti iṣe Yoruba ga
Eegun Zanghetọ