Wákàtí mẹ́ta lẹ́yìn tí Wòsílà bímọ tán pẹ̀lú iṣẹ́-abẹ ni wọ́n j’ọ́mọ gbé lọ

Wosilat Sulaimon

Nnkan bii aago mẹta oru ọjọ kẹsan-an, oṣu kin-in-ni, ọdun 2024 ni obinrin kan, Abilekọ Wosilat Suleiman bimọ ọkunrin nileewosan nipinlẹ Nasarawa, nigba ti yoo si fi di aago mẹfa aarọ, obinrin ajeji kan ti ji ọmọ ikoko naa gbe sa lọ.

Dalhatu Araf Specialist Hospital, Lafia, nipinlẹ Nasarawa ni Wosila bimọ si, iṣẹ abẹ lo fi bimọ naa gẹgẹ bo ṣe sọ.

Bi ọmọ ìkókó ṣe di àwátí lẹyin wakati mẹta to daye

Wosila fomije ṣalaye fun BBC, pe iyawo aburo ọkọ oun to n ran oun lọwọ lọsibitu naa ni awọn dokita gbe ọmọ fun .

O ni nigba to fẹẹ lọọ mu nnkan kan nile lo gbe ọmọ naa fun obinrin kan to ba pade lọsibitu ọhun, to si sọ foun pe obinrin naa yoo maa ran oun lọwọ lọ na.

‘’ Mi o mọ pe ko mọ obinrin yẹn ri to bẹẹ o. Obinrin to ni ko maa ran mi lọwọ sọ pe oun fẹẹ lọọ ba mi wẹ fọmọ mi ni, bo ṣe gbe e lọ niyẹn ti mi o roun atọmọ mi mọ’’

Ṣaja foonu lẹni to yẹ ko maa tọju iya atọmọ lọọ mu nile to fi gbọmọ fẹni ti ko mọ ri

Umar Shehu Nadada,Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa, sọ pe ṣaja foonu ni obinrin to yẹ ko mojuto Wosila atọmọ rẹ lọọ mu nile to fi gbọmọ fobinrin ajeji to gbe ọmọ sa lọ.

Umar fi kun un pe awọn ti mu eeyan mẹta lori iṣẹlẹ yii, obinrin to gbọmọ fun ajeji si wa ninu wọn.

O ni awọn ti pe awọn mi-in naa lati ṣalaye lori iṣẹlẹ yii, awọn oṣiṣẹ ọsibitu naa si n ran awọn lọwọ lori iwadii awọn.

Umar sọ pe oun ko ri apẹẹrẹ ifini-ṣetutu ninu bọmọ naa ṣe dawati, ṣugbọn iwadii n tẹsiwaju.