Antony Blinken:Mínísítà ilẹ̀ òkèèrè ní America sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí ogun Gaza kò ṣe gbọdọ̀ tàn káàkiri

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ninu awọn nkan to ṣe pataki lọkan Minisita ilẹ okeere ni orile-ede America lasiko irinajo rẹ ẹlẹẹkẹẹrin si ilẹ Larubawa laarin oṣu mẹta yii ni isẹ kan to fẹ jẹ níbẹ.
Adisọkan rẹ ni pe ki ogun to n waye laarin Gaza ati Israel ko ma lọ tàn de awọn orileede mii lagbegbe naa.
Bi a ba foju wo bi nkan ṣe n rugbo bọ, apẹẹrẹ wa wi pe o ti n sunmọagbegbe mii.
Ni Yemeni awọn ọmọ ogun ọlọtẹ Houthi ko ti dawọ yíyin ado oloro si awọn awakọ ọkọ oju omi to n kọja ni okun pupa ti eleyi si ṣe idiwọ fun lilọ bibọ awọn ọkọ oju omi lagbaye.
Bẹẹ naa si ni America ti kìlọ pe awọn yoo daabo bo awọn nkan ini awọn.
O ni ti awọn ọmọ ogun ọlọtẹ yii ko ba jawọ ti wọn si n ṣe akoba sí eto ọrọ aje awọn, ko si igba t'awọn ọmọ ogun America ko ni koju wọn.
Bí eyi ba file waye yoo fẹ mu ifasehin wa laarin America ati awọn alabaṣepọ rẹ nilẹ Larubawa.
Esi wo ni Qatar fun un?
Minisita orileede, Qatar Sheikh Mohammed bin Abdulrahman Al- Thani sọ fun awọn akọroyin lasiko to wa pẹlu Antony Blinken pe:
"A ko ri ikoju ologun gẹgẹ bi ọna abayọ"
O ni wahala ti ipa ko ni ka ni yoo da silẹ ni agbegbe naa.
Bawo ni ọ̀rọ̀ ṣe kan Lebanon?
Lọjọ Abamẹta ni awọn ọmọ ogun Hezbollah lagbegbe Guusu Lebanon yin ado oloro pada si ariwa Israel ni idahun si ado oloro kan to jọ pe Israel yin to si sẹkupa ọga Hamas kan ni Beirut.
Israel naa fesi pada pẹlu ado oloro ti wọn dari si awọn ọmọ ologun Hezbollah to wa ni Lebanon.
Imọ̀ran wo lo fun Lebanon?
Lọjọ taa n wi yi, Blinken sọ pe ipenija nla ni ọrọ yi jẹ to si ke si awọn olori lagbegbe to le ba Hezbollah sọrọ ìyẹn Turkey ati Iran lati ke sí wọn lati tọwọ ọmọ bọ aṣọ.
Amọ ati ṣe eleyi yoo lagbara diẹ gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Washington Post ṣe sọ pe awọn alaṣẹ America n kọminu lori pe Israel n gbero lati fẹ oju ikọlu to n ṣe si Hezbollah.
Minisita ọrọ aabo labẹle Israel Yoav Gallant sọ lọjọ Ẹti pe "A nifẹ si yiyanju ọrọ yi ni tuni n nubi ṣugbọn a n sunmọ ibi ti nkan ti le yi pada"
Ẹwẹ, ado oloro lati ọwọ awọn ologun ni Iraq ati Syria ti kọlu awọn ibudo ologun America nibi ti awọn ọmọ ogun America ẹgbẹrun mẹta tẹdo si.
America ti fesi pada to fi mọ sisọ ado oloro lù Baghdad lọsẹ to kọja eyi to pa Mushtaq Taleb al-Saidi,olori ìkọ ologun ọlọtẹ to n gba atilẹyin lọwọ Iran.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olootu ijọba Qatar sọ lọjọ Aiku pe ko le si alaafia ti wọn ko ba wa ọna ijiroro lati yanju ọrọ Palestine.
Ibeere to wa nilẹ bayi ni pe "Njẹ alaafia yi le waye pẹlu ifikunlunkun?"
Lasiko abẹwo rẹ to ṣe loṣu Kọkanla Ọgbẹni Blinken sọ fun awọn akọroyin pe awọn orileede lagbegbe naa ko nifẹ si ogun- ti wọn si n sapa lati ri wi pe ko tan kaakiri.












