Ogun pẹ̀lú Gaza sì ń tẹ̀síwájú - Israel

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ologun orilẹede Israeli ti ni ogun to n waye laarin orilẹede Isreal ati Gaza yoo tẹsiwaju ti ọdun 2024 yoo fi pari.
Ninu ọrọ ikinni ku ọdun tuntun, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun, Daniel Hagari ni awọn ti n se atunse si bi awọn ọmọ ogun yoo se bẹrẹ igbaradi fun ogun ọlọjọ pipẹ.
“Awọn atunse yii lo waye fun igbaradi itẹsiwaju ohun ni ọdun 2024.”
O to ẹgbẹrun mọkanlelogun eeyan, paapa ọmọde ati obinrin ti wọn ti sekupa ni Gaza lati ọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2023 gẹgẹ bi ajọ ẹlẹto ilera Hamas se salaye, ti eeyan to le ni adọtaa ẹgbẹrun si farapa yanayana.
Afikun ti de ba iye eeyan to ti jade laye nitori ogun naa laarin wakati mẹrinlelogun.
Ogun yii lo bẹrẹ lọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2023 lẹyin ti ikọ Hamas sekọlu si guusu Isreal, nibi to le ni ẹgbẹkan eeyan ti jade laye, ti wọn si ji awọn mii gbe.
Lati igba naa ni Israel ti bẹrẹ si ni yin ado oloro si agbegbe Gaza.
O to eeyan mejidinlaadọta to padanu ẹmi wọn ni oorun mọju niluu Gaza lọjọ Aiku, ti minisita fun eto ilera si ni ọpọ awọn eeyan ni ile wo pa mọlẹ tabi ti wọn wa ni abẹ okuta.
Ado oloro mii sekupa oogun eeyan ni fasiti Al-Aqsa niluu Gaza
Olotu ijọba orilẹede Israel, Benjamin Netanyahu ti ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ Hamas lawọn yoo ri pe awọn ran lọ sọrun.
“Gẹgẹ bi olori ọmọ ologun ṣe sọ , ogun yii yoo tẹsiwaju fun ọpọlọpọ oṣu.”















