South Africa gbé Israel lọ ilé-ẹjọ́ àgbáyé lórí ẹ̀sùn ìṣekúpa ọ̀pọ̀ èèyàn ní Gaza

Aworan akọlu ni Gaza

Oríṣun àwòrán, EPA-EFE/REX/SHUTERSTOCK

Orilẹede South Africa ti gbe Israel lọ iwaju ileẹjọ agbaye, ICJ, lori ẹsun iṣekupani ni Gaza.

Ileeẹjọ ajọ iṣọkan agbaye ọhun lo fidi gbigbe iwe ipẹjọ mulẹ lori bi Israel ṣe tapa si asọyepọ tako pipa ẹya run.

Ẹwẹ, Israel lo ti tako ẹsun naa ti Minista fọrọ ilẹ okeere nilẹ naa si wi pe “a tako bi South Africa ṣe n tan ipẹgan ẹlẹjẹ yii ka”.

Ileẹjọ ICJ, to wa ni Hague lorilẹede Netherlands ni ẹka idajọ to ga julọ lajọ iṣọkan agbaye, to si maa n da si aawọ laarin orileẹde, ti wọn si tun maa n fun wọn lamọran lori ofin agbaye.

Lẹyin to pe ẹjọ naa si ICJ, ileṣẹ aarẹ ilẹ South Africa lo wi pe “lati pinwọ ipanirun ni a duro fun”.

O wi pe, “South Africa kọminu gidi lori awọn araalu ti ogun naa kamọ Gaza ninu akọlu Israel sagbegbe naa ni bi wọn ṣe n lo ipa ati agbara lai bikita lati fi gbe awọn olugbe ibẹ kuro.

“Siwaju sii, a n gbọ iroyin pe awọn iwa ilufin ogun, titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ, atawọn iwa miran to nii ṣe pẹlu pipa ẹya kan run ti waye, to si ṣeeṣe ko tun maa waye lọwọ ninu awọn iṣekupani to n lọ ni Gaza.”

Iwe ipẹjọ naa to loju ewe mẹrinlelọgọrin lo wi pe “gbogbo ohun ti Israel n ṣe lagbegbe naa lo jọ bii pe wọn fẹẹ mọọmọ mu iparun ba iran ati ẹya kan ni Palestine”.

Wọn waa rọ ICJ lati gbọ ẹjọ na lọsẹ to n bọ, ki wọn si fi awọn ofin kan de Israel lati pinwọ ogun ni Gaza.

Lior Haiat, to gbẹnusọ fun ileeṣẹ ilẹ okeere lorilẹede Israel wi pe South Africa lo kan n fi “ilara ati ẹgan wa ohun ti ko sọnu niwaju ileẹjọ naa”.

Haiat wi pe South Africa n “lẹdi apo pọ mawọn ẹgbẹ agbesunmọmi to n pe fun iparun israel”, ati pe Hamas “lo wa nidi ijiya awọn ọmọ Palestine to n gbe ni Gaza latari bi wọn ṣe n fi wọn boju, ti wọn si n ji awọn ohun iranwọ ti wọn ri gba”.

“Israel lo n tẹlegbogbo ilana ofin lagbaye to si ti paa laṣẹ fawọn ọmọgun rẹ lati doju ija kọ awọn Hamas nikan ati ẹgbẹ agbesunmọmi to ba ṣe iranwọ abi atilẹyin fun wọn.”

South Africa koro oju si ohun to n ṣẹlẹ ni Gaza

Lati oṣu kọkanla ni South Africa ti pe awọn aṣoju ijọba rẹ to wa ni Israel pada wale, ti Israel naa si fesi nipa pipe olori aṣoju ilẹ naa ni South Africa pada lati Pretoria.

Bakan naa ni ile aṣofin apapọ South Africa fẹnu ko si ki wọn piwọn ibaṣepọ pẹlu Israel, amọ ti ijọba ko tii gbe igbẹsẹ yii.

South Africa lo ti kọkọ lọ si ileẹjọ awọn ọdaran lagbaye, ICC, lori ọrọ ogun naa amọ Israel ko ka ileẹjọ naa kun nkankan.

Ogun to n lọ lọwọ laarin Israel ati Hamas lo bẹrẹ pẹlu akọlu Hamas si guusu Israel lọjọ keje, oṣu kẹwaa, ọdun 2023, nibi ti wọn ti ṣekupa awọn bii ẹgbẹfa – ti pupọ ninu wọn jẹ araalu – ti wọn si ko awọn bii ojilerugba lọ.

O le ni ẹgbẹrun mọkanlelogun ati ẹẹdẹgbẹta eeyan ti wọn ti padanu ẹmi wọn ni Gaza lati igba naa – ti pupọ ninu wọn jẹ obinrin ati ọmọde – ninu akọlu ẹsan ti Israel ṣe si Gaza gẹgẹ bii ileeṣẹ eto ilera ti Hamas n dari rẹ ṣe wi.