''Qatar kò ní dẹ́kun ìgbìyànjú rẹ̀ láti parí ogun tó ń lọ́wọ́ ní Gaza''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olootu ijoba orilẹede Qatar, Sheikh Mohammad bin AbdulRahman al-Thani ni orilẹede Qatar ko ni dẹkun igbiyanju rẹ lati parí ogun to wa laarin Gaza ati ilẹ Israel.
Sheikh Mohammad bin AbdulRahman al-Thani sọ eyi níbi ipade Doha.
Bẹẹ ba gbagbe orilẹede Qatar ko ọpọlọpọ ipa ninu bí itusilẹ awọn ẹlẹwọn ṣe waye laarin orilẹede mejeeji ninu oṣu kọkanla.
Olotu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu sọ laipẹ yii Ogun naa si n tẹsiwaju.
O ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun awọn ọmọ ogun Hamas lo ti juwọ ohun ija silẹ, ti wọn si fara wọn kalẹ.
"Ibeere opin Hamas ree, " o salaye.
Lọjọ Aiku, ajọ to n risi ìlera ni Gaza ni o to ẹgbẹrun mejidinlogun ọmọ ilẹ Palestinian ti wọn ti ṣekúpa.
Ninu ohun ti wọn fi ransẹ si Al Jazeera, ikọ ogun Hamas ni bi wọn ṣe tu awọn ẹlẹwọn fi fihan pe awọn ṣe otitọ ati pe awọn ko ni tu awọn mii silẹ mọ ayafi ti Israel ba setan lati sọrọ.
Nigba to n sọrọ. Abu Ubaida sọ pe ikọ ologun Hamas tí ba ohun ija jẹ pupọ, ti wọn dẹ tun ṣekúpa ọpọlọpọ ọmọ ogun Israel, to si jẹ pe eyi lo bí Israel ninu awon.
Lẹyin ipade ni Doha, Philippines Lazzarini, olori ajọ UNRWA ni agbegbe Gaza tí di ọrun apadi lori ilẹ aye, to si ohun buruku tí yoo foju rí laye rẹ.
Ní bayi Ilu Khan Younis, ibi tí wọn ni kí eeyan salo sí lasiko ti wọn se kọlu si apa ariwa Gaza naa ti fiba ibu gbamu, ti Israel sì n rọ àwọn araalu lati kuro ni agbegbe naa.
Nigna to n ba BBC News sọrọ, onidamọran agba ni ilẹ Israel, Mark Regev ni ogun naa ni yoo waye ni Khan Younis, to si rọ àwọn ọmọ ilu lati kuro ni agbegbe naa lọ sí ibi tí alaafia wa.
Ajọ to n risi eto ìlera lagbaye naa ti gbe igbesẹ lati le fun awọn eeyan ni anfani si eto ilera ni kiakia.












