Obama kéde àwọn orin tó gbádùn ju lọ́dún 2023, àwọn orin wo lẹ̀yin fẹ́ràn jùlọ lọ́dún yìí?

Oríṣun àwòrán, Barack Obama/Facebook
Aarẹ tẹlẹ ri lorilẹede America, Barack Obama, lo ti fi awọn orin kan lede bii orin ti oun gbadun julọ lọdun 2023.
Obama, lati igba to ti kuro lori aleefa bi aarẹ, lo maa fi awọn orin kan lede nipari ọdun pe awọn loun gbadun rẹ ju ninu ọdun naa.
Eyi lo si maa n fa ọpọlọpọ itakunrọsọ nipa awọn koko to wa ninu awọn orin ọhun ati bi awọn akọrin to kọ wọn ṣe lo igbesi aye wọn laarin ọdun naa.
Bakan naa ni awọn ọdọ jakejado agbaye maa n sọ eyi tawọn naa nifẹ si ninu awọn orin naa ati id ti wọn fi yan wọn laayo.
Eyi ko tumọ si pe awọn agbalagba atawọn ilumọọka oloṣelu naa kii da si ọrọ ohun nitori irufẹ eniyan ti Barack Obama jẹ.
Ninu ọdun yii awọn orin mejidinlọgbọn ni Obama fi lede, ti mẹrin ninu rẹ si jẹ orin ti awọn ọmọ Naijiria kọ.
Awọn orin to jẹ ti Nijiria nibe ni ‘Unavailable’ latọwọ Davido, ‘Sittin’ On Top Of The World’ latọwọ Burna Boy, ‘Amapiano’ ti Asake kọ, ati ‘Me & U’ latẹnu Tems.
Yatọ si awọn orin yii, Obama tun fi awọn fiimu ati iwe to gbadun ninu ọdun 2023 lede.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















