'Bàbá Ada' gún Philip pa nítorí obìnrin ní ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, BBC/others
Titi di asiko yii lawọn eeyan ṣi n daro iku ojiji to pa baale ile kan, Philip Fiama, ẹni ti ayalegbe bii tirẹ gun lọbẹ laya nitori obinrin, nilu Ajuwọn, ni ipinlẹ Ogun lẹkun iwọ oorun gusu Naijiria.
Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Samuel Achelenu, to jẹ ọrẹ timọtimọ fun Oloogbe Philip, ṣalaye fun BBC pe Ikem Emmanuel, lẹni to gun ọrẹ oun pa.
O ni Baba Ada lawọn mọ Ikem si, ile kan naa loun ati Philip n gbe.
Philip fẹsun kan Baba Ada pe o n ba iyawo oun sun lo ṣe gun un pa

Gẹgẹ bi Samuel ṣe ṣalaye, ’’ Gbogbo wa la ti n gbọ finrin-finrin pe Baba Ada n ba iyawo Philip sun. Philip funra ẹ naa dẹ ti gbọ lo ṣe ko Baba Ada loju lọjọ Sannde to kọja.
‘’ Emi ati Philip la jọ de lati pati lọjọ Sannde yẹn, mo gba ile temi lọ ninu opopona kan naa ta a jọ n gbe. Mo si lero pe ma a waa ba a laaarọ ọjọ keji ka jọ maa lọ s’Ọbalende ta a ti n fi Korope ko ero.
‘’Igba ti mo debẹ ni mo gbọ pe Baba Ada gun un lọbẹ laya lalẹ ọjọ yẹn, nitori Philip ko o loju pe o n ba iyawo oun sun.
Bo ṣe gun un lọbẹ naa lo dẹ ti sa lọ ti a ko ri i mọ’’
Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa Ogun wi

SP Ọmọlọla Odutola, Alukoro ọlọpaa Ogun, sọ pe lanlọọdu ile awon Philip lo fi iṣẹlẹ naa to awọn leti.
Sobande Close, Alagbole, Ajuwọn lo ni ile naa wa.
Alukoro sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori rẹ, bẹẹ ni iṣẹ ti n lọ lati mu afurasi to gun Philip pa.
Ọmọ ipinlẹ Adamawa ni Philip, iwadii fi ye wa pe ọmọ mẹta loun atiyawo rẹ tawọn eeyan mọ si Iya Matthew bi.
Ṣagamu ni wọn n gbe tẹlẹ gẹgẹ bi iwadii ṣe fidi ẹ mulẹ, aṣemaṣe Iya Matthew pẹlu awọn ọkunrin adugbo la gbọ o fa a ti lanlọọdu fi fun wọn niwee, ti wọn fi ko wa si Ajuwọn,nitosi Alagboole.












