Fún àwọn agbébọn, à wa gan kò 'Gree'- Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà

Aworan

Oríṣun àwòrán, Facebook/HQ Nigerian Army

Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti sọ fun ọmọ orilẹede Naijiria pe ki wọn rí gbigbe ogun ti agbebọn gẹgẹ ohun a fọwọsowọpọ ṣe, ti wọn ede pidgin ti awọn ọdọ yan layo 'No gree for anybody'.

Ọrọ 'No gree for anybody' lo tumọ si pe ki ma ṣe gba fun ẹnikẹni.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun, Ọgagun Edward Buba lo sọrọ yii niluu Abuja lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ.

O ni ileeṣẹ ologun setan lati sisẹ pọ pẹlu awọn ọmọ Naijiria lati gbe ogun ti awọn agbebọn to n da agbegbe lamu.

"Lọdun 2024 yii, mo rọ awọn araalu lati abo ilu gẹgẹ bii ajọsepọ wa.

"Lati akọkọ yii, ẹ ma gree fun awọn agbebọn.

"Ti ẹ ba ri nnkan ẹ sọ fun wa, ẹ duro digbi ni agbegbe yín."

O wa jẹ ko di mimọ pe erongba ileeṣẹ ologun ko yi pada, ti yoo ṣíṣe ju ti tẹlẹ lọdun 2024.

"Erongba wa ni lati wa awọn agbebọn yii, ka si pawọn rẹ nibikibi ti wọn ba sa pamọ si. Eyi ko ni fun wọn ní anfani lati se aburu si awọn araalu.

"A ko ni dẹkun ti a o fi ripe a jẹ pawọn rẹ."

Ẹ yàgò bíbá wọn dá àṣà 'no gree for anybody' iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sàlàyé ìdí tó fí léwu lásìkò yìí

Aworan Olumuyiwa Adejobi

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police

Ṣaṣa lẹni ti ko ni ti gbọ nípa aṣa kan to gbode lẹnu ọjọ diẹ ti a bẹrẹ ọdun 2024 yi.

Koda o ṣeeṣe ki eeyan kan maa da aṣa naa lọwọ ba ṣe n sagbekalẹ iroyin yi.

Bi o ba wa ninu awọn to n ba wọn da laṣa ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni ko jawọ nidi rẹ.

Alukoro ọlọpaa Naijiria l'awọn koro oju si aṣa yi ti o gba ẹnu ọpọ awọn ọdọ Naijiria.

Olumuyiwa Adejobi lo fidi ọrọ yi mulẹ

to si ni awọn ko ni bikita lati kọdi awọn eeyan lati maa da aṣa yi .

Ni Ọjọru nibi to ti n ba awọn akọroyin sọrọ lo ti sọ pe iroyin de eti igbọ awọn eyi to tọka si pe o ṣeeṣe ki aṣa yi da gbọn mi si omi o to silẹ lorileede Naijiria.

O ni lati ọdọ awọn alakatakiti kan ni lorileede Naijiria l'awọn gbọ iroyin pe aṣa yi ti sẹ wa.

O tẹsiwaju pe aṣa yi le dabi ẹni dapara lasan ṣugbọn " lọdọ awa taa mọ nipa eto aabo, aṣa yi le ṣe atọna idasilẹ yanpọnyanri lawujọ "

Ki ni orisun aṣa yi?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Adejobi sọ pe awọn mọ pe orisun aṣa yi ni orin ẹmi ti Sister Agatha Moses gbe jade ti akọle rẹ n jẹ "I no go gree"

Iwadii fi han pe orin yi le jẹ ki aṣa naa gbode ṣugbọn gbolohun ' I no go gree' to tunmọ si mi o ni gba jẹ eleyi tàwọn eeyan ko ṣẹṣẹ ma lo ni Naijiria.

Aṣa yi t'awọn eeyan mu ni orin akọmọna tunmọ si oríṣi nkan ti a sí ti n ri alaye orisi t'awọn eeyan n fun gbolohun I no go gree.

Yala ninu aworan,fidio tabi ere apanilẹrin itunmọ to jọ pe awọn eeyan n fun I no gree ni pe, mi o ni gba, mo maa f'ẹsẹ mi rinlẹ ni lori nkan ti mo lero pe o jẹ ẹtọ mii.

A ko lero pe eleyi ni itunmọ ti ileeṣẹ ọlọpaa mẹnu ba tori awọn sọ pe o le da rugudu ti yoo tan kaakiri Naijiria.

Eyi to han si wa ni pe awọn ọdọ Naijiria lo n lọ aṣa yi julọ.

Ti a ba wo wipe awọn aṣa mii to awọn ọdọ Naijiria gbe larugẹ bi "Sorosoke" di ilumọoka lasiko iwọde Endsars,o ṣeeṣe ki awọn ọlọpaa maa ti ati okere sunkun oloju jinjin ki o to di itẹwọgbà fawọn ọdọ nibi iwọde mii.

Lootọ Olumuyiwa Adejobi ko sọrọ lọ sidi Endsars to waye lasiko to koro oju si aṣa I no go gree.

Boya eleyi lo wa fi n sọ oko ọrọ a ko le sọ ṣugbọn awọn ọdọ ti n fesi loju opo Twitter si ikilọ to fi sita nipa lilo aṣa I no go gree

Gbogbo nkan lo n d'ẹru ba yín, a o ni gba

Loju opo ayelujara X, Twitter, awọn ọdọ Naijiria ti bẹrẹ si ni fi ero wọn ranṣẹ si oga Olumuyiwa Adejobi lori ọrọ to sọ.

Pupọ ni ko ri ọrọ yi bi awada ti wọn si ni ko yẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa maa bẹrù lori apara tàwọn eeyan n da lasan.

Diẹ ree ninu awọn esi taa ri ni Twitter

Aworan esi tàwọn eeyan fọ sí ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, X Twitter screen shot

Aworan esi awọn araalu sí ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, X Twitter screenshot