Àfàìmọ̀ káwọn tó pa Bola Ige má pa Olu Agunloye náà- Wole Soyinka

Aworan Olu Agunloye ati Wole Soyinka

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook

Ilumọọka onkọwe n ni, Ọjọgbọn Wole Soyinka ti koro oju si bi wọn ti gbe minisita ina mọnamọna ati irin inu ilẹ tẹlẹ ri, Olu Agunloye sí ọgbà ẹwọn to wa ni Kuje niluu Abuja.

Ni Ọjọru ni wọn gbe Ọgbẹni Agunloye lọ sile ẹjọ lori ẹsun iwa ajẹbanu ti wọn fi kan an.

Adajọ ileẹjọ ijọba apapọ naa niluu Abuja pàṣẹ pe ki wọn gbe Agunloye lọ sí ẹwọn ni Kuje titi ti wọn yoo fi gba beeli rẹ.

Amọ, Soyinka kọminu ninu atejade kan to fi sita lori aabo minisita tẹlẹ ri naa ni ọgba ẹwọn ti wọn fi si.

Soyinka ni awọn to pa minisita eto idajọ tẹlẹ ri, Bola Ige lọdun 2001 tun le ṣekupa Agunloye naa.

"O wu mi lati ṣe itaniji fun orilẹ ede Naijiria ati ijọba mo n kọminu lori aabo Agunloye.

Awọn agbenipa ni wọn pa Oloye Bola Ige to jẹ minisita ina mọnamọna tẹlẹ lasiko tawon ọlọpaa to n ṣọ ọ lọ jẹun.

To fi di oni, a o mọ awọn to ṣekupa Ige.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Mo ti sọ laipẹ yii pe lori ọrọ jibiti akanṣe ileeṣẹ mọnamọna Mambilla ni wọn pa Bola Ige le lori.

Olu Agunloye ṣiṣẹ pọ pẹlu mi lati ṣe iwadii ati lati ṣe awari awọn to pa Ige.

Iwa omugọ lo maa jẹ lati ro pe awọn to pa Bola Ige le ṣekupa Agunloye naa.

Eleyii ṣi le di ṣiṣe pẹlu bi wọn ṣe gbe e ju sẹwọn lojiji.

Ẹ jẹ ki o ye gbogbo eeyan pe ti ohun kan ba ṣẹlẹ si ẹni to jẹ ẹlẹrìí gidi ni ahamọ, nigba naa ọrọ yii yoo ye onikaluku daadaa," Soyinka ṣalaye.

Soyinka ti pe fun igbimọ oluwadii aladani tẹlẹ lati ṣe iwadii jibiti akanṣe iṣẹ ina mọnamọna eleyii to ti ṣakoba fun gbogbo ọmọ Naijiria fun bi ogun ọdun bayii.

Ni oṣu Kejila ọdun 2023 ni ajọ EFCC kede pe awọn n wa Agunloye lori ẹsun iwe yiyi ati iwa ajebanu.

Leyin naa ni wọn fi ọwọ ofin mu Agunloye, wọn si ti i mọle.

Ohun ti a gbọ ni pe ajọ EFCC ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Agunloye to ṣe minisita labẹ ijọba aarẹ Olusegun Obasanjo lori akanṣe iṣẹ mọnamọna Mambilla.

Ẹwẹ, Obasanjo ti kọkọ fẹsun kan Agunloye pe o gbe iṣẹ akanṣe ileeṣẹ mọnamọna fun kọngila lai gba ibuwọlu lati ọwọ igbimọ alaṣẹ ijọba Naijiria.

Amọ, Agunloye fesi pe ọrọ ko ri bẹẹ, o ni ko si otitọ ninu ọrọ Obasanjo.