Ìbẹ̀rùbojo ni Bàbá mi TB Joshua fi lo ayé rẹ̀ bí ẹni pé àṣìrì rẹ̀ yóò tú lójijì- Ajoke, ọmọ TB Joshua

Ajọkẹ Joshua jẹ ọmọ bibi inu Pasitọ T.B Joshua ti a ko mọ pupọ nipa iya to bi i.
Arabinrin Evelyn ti i ṣe opo T.B Joshua bayii lo tọ ọ dagba, ọmọ ijọ to loyun fun Joshua lo bi Ajọkẹ ni ohun ti a ri.
Ajọkẹ ni ẹni akọkọ to ta BBC lolobo nipa awọn iṣẹlẹ to lodi siwa ọmọluabi to n ṣẹlẹ nileejọsin Sinagọgu, to fi dohun ti iṣẹ iwadii ọlọdun meji BBC yii bẹrẹ ni SCOAN gan-an.
Ajoke sọ fun BBC pe:.......
‘’ Ni gbogbo igba lọkan baba mi ki i balẹ, niṣe lo maa n ṣe bii pe ẹnikan n bọ to maa waa tu aṣiri awọn iṣẹ laabi rẹ.
‘’Ki n too pe ọmọ ọdun meje, igbesi aye alaafia ni mo n gbe pẹlu idile Joshua, a maa n gbafẹ lọ sorilẹ-ede Dubai atawọn ibo mi-in.
‘’Ọjọ kan ni gbogbo nnkan yi pada, wọn da mi duro nile ẹkọ nitori aṣemaṣe kan,
akọroyin kan si kọ ọ pe ọmọ ale ni mi fun T.B Joshua, bi wọn ṣe mu mi kuro nile ẹkọ niyẹn lọ sinu ọgba ileejọsin SCOAN.
Ajoke tun ṣalaye pe: " Wọn fi mi si yara awọn ọmọlẹyin T.B Joshua, awọn ti wọn ko le daye ara wọn gbe.
Wọn ko le sun kọja asiko ti wọn ba fun wọn, wọn ko le lo foonu wọn pẹlu.
Wọn ti di didinrin kalẹ, kaakiri agbaye ni wọn si ti wa, wọn fipa mu wọn lati maa pe T.B Joshua ni baba.
Wọn o si le beere ohunkohun.
‘’Emi o fẹẹ jẹ ọmọlẹyin T.B Joshua, mo tako gbogbo ohun ti wọn n fipa mu wọn lati ṣe, mi o dẹ ki n dide bii awọn yooku ti Joshua ba wọle waa ba wa.
‘’Mo tako wọn, wọn ni ẹlẹmi okunkun ni mi
Ko pẹ sigba naa ni wọn bẹrẹ si i lu mi nitori mo tako ohun ti wọn n ṣe, wọn ni ẹmi okunkun wa lara mi.
Ọmọ ọdun meje ni mi, ti mo ba tọ sile, wọn maa lu mi, wọn n tun paṣẹ pe kẹnikẹni to ba ri mi ko maa lu mi.
Wọn kọ akọle ‘Atọọle ni mi’ sinu patako wọn si gbe e kọ mi lọrun lati maa gbe kiri kawọn eeyan le mọ pe mo n tọ sile.
Rae, ọkan ninu awọn ọmọlẹyin T.B Joshua, sọ pe oju oun lo ṣe nigba ti Baba Ajọkẹ n fiya jẹ ẹ to si ni kawọn maa lu u.
Ajọkẹ ṣalaye pe oun farada iya naa titi toun fi pe ẹni ọdun mẹtadinlogun (17), toun si dide lọjọ kan lati ko baba oun loju.
‘’Ọmọlẹyin Joshua kan mu mi lọ sidi ẹrọ lati wẹ, o si bẹrẹ si i fi waya ina na mi,
o ṣi omi gbigbona le mi lori, o fi mi silẹ lọ bi mo ṣe n pariwo to.
Mo foju mi ri bi baba mi ṣe maa n ba awọn obinrin ijọ ṣe iṣekuṣe

Ajoke tun sọ pe:
" Mo ri bi awọn ọmọ ẹyin T.B Joshua obinrin ṣe maa n wọ yara rẹ lọ fun ọpọlọpọ wakati.
Bẹẹ ni mo maa n gbọ tawọn mi-in yoo sọ pe Joshua fẹẹ ba awọn lo pọ.
Ọpọlọpọ wọn lo jẹ ohun kan naa ti wọn n sọ niyẹn.
Kini awọn ọmọléyin TB Joshau tun sọ fun BBC?
BBC fọrọ wa awọn ọmọ ẹyin T.B Joshua ti wọn le ni mẹẹẹdọgbọn sọrọ lori ẹsun ifipabanilopọ yii, lati awọn orilẹ-ede bii UK, Nigeria, US, South Africa, Ghana, Namibia ati Germany, gbogbo wọn ni wọn sọ bi Joshua ṣe ba wọn ṣere ifẹ lai ti ọkan wọn wa.
" Mo gba ọfiisi rẹ lọ mo si pariwo le e lori pe ki lo de to n ṣe bayii sawọn obinrin, ki lo de to n ni wọn lara.
‘’Ẹru kankan ko ba mi mọ nipa ọkunrin yii, mo ko o loju, o fẹẹ ki n dakẹ ṣugbọn mi o gba fun un.
Nigba to n fidi eyi mulẹ, Emmanuel, ọkan lara awọn ọmọ ẹyin T.B Joshua to ti lo ju ọdun mọkanlelogun lọ ninu ijọ naa sọ pe, "TB Joshua lo kọkọ bẹrẹ si i lu Ajọkẹ lọjọ yẹn, awọn yooku naa wa bẹrẹ si i lu u.
'Joshua n sọ pe ṣe o yẹ kọmọ oun maa sọ iru nnkan bayii nipa oun?, bẹẹ lo n lu Ajọkẹ lọ, ṣugbọn ọmọ naa ko yee sọrọ.
Ajọkẹ sọ pe iṣẹlẹ ọjọ naa lo jẹ ki wọn fi oun pamọ sinuu yara kan lai jade sita.
O ni o ju ọdun kan lọ toun fi wa lahaamọ naa.
Ijiya ahamọ yii ni T.B Joshua maa n fun awọn eeyan to ba ṣẹ ẹ. ‘adaba’ ni wọn n pe ijiya naa nibẹ.
Bi wọn ṣe ti mi mọle ni wọn n lu mi lojoojumọ

Awọn nnkan bii bẹliiti ati ṣeeni l’Ajọkẹ sọ pe wọn maa n waa fi lu oun mọ inuu yara naa lojoojumọ.
" Mi o mọ bi mo ṣe gbele aye lasiko naa, mi o tiẹ ki n le da duro lẹyin ti wọn ba lu mi tan,
koda, mi o ki n le wẹ.
Ohun to ṣaa n fẹ ni pe kawọn eeyan ma gbọ ohun ti mo n sọ nipa rẹ.
Nigba ti ijiya naa yoo dopin, Ajọkẹ sọ pe oun wa lẹni ọdun mọkandinlogun ni wọn waa mu oun jade ninu yara naa lọjọ kan.
O ni wọn sin oun de ẹnu geeti ṣọọṣi Sinagọgu wọn si fi oun silẹ sibẹ.
Wọn sọ fawọn aṣọgba pe wọn ko gbọdọ jẹ koun wọle sileejọsin naa mọ laye.
‘’Mi o nile, mi o leeyan, mi o lẹni ti yoo gbọ ẹjọ mi. Aye su mi!
Igbese wo ni Ajoke ti gbe?
Ajọkẹ ti pe ọdun mẹtadinlọgbọn (27) bayii, o si ti yọ Joshua kuro ninu orukọ rẹ.
O loun gbiyanju, oun ṣẹgun iṣoro arinkiri, oun si wọna lati ba BBC sọrọ ni 2019, lẹyin toun wo iṣẹ iwadii wọn kan to tu aṣiri iṣẹ ibi.
Ajọkẹ ba BBC sọrọ, iṣẹ iwadii abẹnu to kẹnu si bẹrẹ lori awọn nnkan wọnyi, o si pada dohun taye n ri aworan ati ijẹrisi rẹ lori afẹfẹ loṣu kin-in-ni, ọdun 2024.
Bo tilẹ jẹ pe iya tọmọbinrin naa jẹ ti n nipa lori ironu rẹ gẹgẹ bi eeyan, ṣibẹ, bo ṣẹ ko baba rẹ loju, fun awọn ọmọlẹyin T.B Joshua yooku nigboya lati sọrọ pẹlu, wọn si jẹwọ pe Ajọkẹ lakọni to jẹ ki awọn le ronu ati sọrọ jade.














