Yahaya Bello rọ ọba alayé mẹ́rin lóyè ní Kogi

Oríṣun àwòrán, Yahaya Bello/Facebook
Ọba alaye mẹrin, eyi ti onipo kin-in-ni wa ninu wọn ni Gomina Yahaya Bello tipinlẹ Kogi ti rọ loye bayii.
Lara awọn ọba tọrọ naa kan ni Ohimege Igu, Konto-Nkarfe ati Alhaji Abdulrazaq Koto.
Alhaji Salihu Seidu tawọn eeyan mọ si SAS lo rọpo Ohimege.
Gomina paṣẹ ki wọn tete fi i jẹ oye naa, kori itẹ maa baa ṣi silẹ lai lọba.
Yatọ sawọn ọba ti gomina rọ loye, Yahaya Bello tun kede iyansipo Alhaji Ahmed Anaje, ẹni ti i ṣe Ohi Okenwen tẹlẹ gẹgẹ bi Ohinoyi ilẹ Ebira bayii.
Nigba to n ṣalaye idi to fi gbe awọn igbesẹ yii, Yahaya sọ pe awuyewuye pọ lori awọn ipo naa, bẹẹ ni iwoye ijọba lori wọn ṣe koko.
Awọn mi-in ti gomina juwe ile fun ni
Ọba Sam Bola Ojoa, Olu Magongo ti Magongo.
Ọba Samuel Adayi Onimisi, Obobanyi ti Emani.
Ọba Boniface Musa,Onu-Ife nijọba ibilẹ Omala,Yahaya Bello yọ ọ nipo lai nigba kan ti yoo pada sori itẹ.
Awọn to gba ipo tuntun
Alhaji Ibrahim Gambo Kabir, Maigari ti Lokoja.
Alhaji Dauda Isah, Maiyaki tiluu Kupa.
Mallam Saidu Akawo Salihu,Ohimege-Igu Koton-Karfe.
Gomina Yahaya Bello tun fontẹ lu oye Ohi of Uhuodo, o ni oye ilẹ Ebira ni, ki eto nipa jijẹ oye naa bẹrẹ laipẹ.













