Ẹ ò gbọdọ̀ gbowó àìtọ́ lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ - Ìjọba Oyo kìlọ̀ fáwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ ìjọba

Awon akekoo ni kilaasi

Oríṣun àwòrán, Others

Kọmisana fun eto ẹkọ, imọ sayẹnsi ati ẹrọ igbalode n'ipinlẹ Ọyọ, Ọjọgbọn Salihu Adelabu ti fi ikilọ lede fun gbogbo awọn adari ile ẹkọ ijọba ati awọn olukọ lati ṣọra fun gbigba owo lọna aitọ lọwọ awọn akẹkọọ.

Adelabu ṣe ikilọ yii nilu Ibadan lọjọ Aje lasiko to n mojuto iwọle pada sẹnu ẹkọ awọn akẹkọọ lẹyin ti ọlude ọdun pari.

Kọmisana naa parọwa si awọn akẹkọọ lati fi oju si ẹkọ wọn, gẹgẹ bi o ṣe n rọ awọn olukọ wọn lati ṣiṣẹ wọn bi o ṣe tọ nipa kikọ awọn akẹkọọ naa nilana igbalode.

Oluko ni kilaasi atawon osise ijoba

Oríṣun àwòrán, OYST

O ni, "Oni ni ọjọ akọkọ ti gbogbo ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama wọle pada ni ipinlẹ Ọyọ.

Itara awọn olukọ ati akẹkọọ ti a ri tẹ wa lọrun.

Ohun ti a ri fi idi rẹ mulẹ wi pe o kere tan, ida aadọrin awọn akẹkọọ lo ti pada si ẹnu ẹkọ wọn, bẹẹ sini awọn olukọ ati awọn oṣiṣẹ mii ti o ti pada sẹnu iṣẹ wọn to ida mẹtadinlọgọrun."

"Mo fẹ ṣe ikilọ fun awọn olukọ pe wọn ko gbudọ ni ki akẹkọọ tabi obi kankan san owo lona aitọ nitori ọfẹ ni eto ẹkọ ni ipinlẹ Ọyọ.

A rọ awọn obi ti ọmọ wọn ko tii pada sẹnu ẹkọ lati yara ṣe bẹẹ nitori eto ẹkọ ti bẹrẹ pada ni pẹrẹu."

Lara awọn ile ẹkọ ti Kọmsana naa ṣe abẹwo si ni: Ọba Akinbiyi Model School, Mokola, St. Louis Grammar School, Mokola, Government Secondary School, Orita-Aperin, Ibadan ati bẹẹ bẹẹ lọ.