Mohbad: Inú mi ò dùn sí ìwádìí Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá - Baba Mohbad

Oríṣun àwòrán, BBC/Others
Joseph Aloba,baba gbajugbaja olorin takasufe to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba tí ọpọ mọ si Mohbad tí jẹ ko di mimọ pe inu ko dun sí ìwadii ileeṣẹ Ọlọpaa lori ohun to sokunfa iku ọmọ rẹ.
Ninu oṣu kẹjọ ọdun 2023 ni Mohbad, to jẹ akọrin labẹ ileeṣẹ olorin tí Azeez Fashola tí ọpọ mọ si Naira Marley jade laye ni ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn nipinlẹ Eko.
Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Eko, lọjọ kejidinlogun gbe ìgbìmọ ẹlẹni metala lati ṣe ìwadii.
Lasiko to n ba Trust TV sọrọ, JosepJoseph Aloba ni ọpọlọpọ nnkan awọn eeyan n sọ to si jẹ pe o jinna si otitọ.
O salaye pe gbogbo erongba ohun lẹyin ti wọn hu oku Mohbad ni pe wọn yoo lọ ṣe ìwadii ni ile rẹ.
Aloba tun wa bu ẹnu atẹlu bi ko se ti ni anfani si esi ayẹwo oku ọmọ rẹ.
"Inu mi o dun pẹlu iwadii ileeṣẹ Ọlọpaa. Nigba ti mo gbe oku Mohbad lọ si agọ Ọlọpaa, gbogbo erongba mi pe wọn yoo tẹle mi lọ ile Mohbad lati lọ ṣe ìwadii tabi fun mi ni esi ayẹwo oku rẹ.
"A ni lati bere awọn ibeere kan lọwọ awọn eeyan ti wọn jọ wa papọ. Ẹ yẹ foonu wọn wo, wọn mọ ohun to ṣekupa Mohbad.
"Ọpọlọpọ eeyan lo n gbe pẹlu Mohbad.
Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko ti jẹ ko di mimọ pe awọn si n retí esi ayẹwo Autopsy ti wọn ṣe lati mọ ohun to sekupa pa gbajugbaja olorin takasufe, Ilerioluwa Aloba, tí ọpọ eeyan mọ si Mohbad.
Bakan naa ni Ileeṣẹ Ọlọpaa tí ransẹ pe awọn afurasi lori iku olorin naa lati le tan imọlẹ si iwadii wọn.















