Ọlọ́pàá ti dá sí ìjà tó ń wáyé láàrín Tiwa Savage àti Davido.

Oríṣun àwòrán, Getty
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fidi ẹ mulẹ, pe awọn ti gba iwe ifisun ti obinrin akọrin nni, Tiwa Savage, kọ sawọn nipa David Adeleke( Davido).
Tiwa sọ fọlọpaa pe Davido n dunkooko mọ ẹmi oun, o si n ba oun lorukọ jẹ pẹlu.
Ija to deede bẹ silẹ laarin awọn olorin sufee-taka meji yii ti le debii pe wọn ki i ṣe ọrẹ ara wọn mọ lori ayelujara.
Ki lo fa ija Tiwa ati Davido?
Ohun to fa ija naa gẹgẹ bi Tiwa ṣe ṣalaye, ni fọto kan toun ya pẹlu ọkan lara awọn obinrin to bimọ fun Davido, iyẹn Sophia Momodu.
O loun gbe fọto naa soju opo Instagraamu oun lori ayelujara.
‘’ Latigba ti mo ti gbe fọto yẹn sibẹ ni Davido ti bẹrẹ si i sọrọ buruku si mi, bẹẹ lo n fọrọ buruku ranṣẹ si maneja mi naa.
‘’Awọn eeyan to sunmọ emi ati Davido gan-an ti n beere pe ki ni mo ṣe fun un to fi n binu si mi bẹẹ, to tun n sọrọ arifin si mi.
‘’Wọn ni Davido n binu pe mo n ba Sophia to bimọ kan fun un ṣọrẹ, nigba to jẹ pe aarin Sophia ati Davido ko gun mọ.’’

Oríṣun àwòrán, facebook
Ninu iwe ifisun ti Tiwa kọ sawọn ọlọpaa lo ti sọ pe Davido fẹẹ kaye maa ri oun Tiwa Savage bi ẹni to n da wahala silẹ, bẹẹ ipe oriṣiiriṣii loun ti n gba latigba toun ti gbe fọto ọhun jade.
Tiwa ṣalaye bo ṣe jẹ pe ọrẹ oun ni Davido latilẹ, toun si duro ti i ṣinṣin lasikoto padanu ọmọ rẹ, Ifeanyi ni 2022.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, sọ fun BBC pe awọn yoo bẹrẹ iṣẹ lori ifisun yii, nitori ontẹ awọn ti wa lori ẹ digbi.














