CBN fọwọ́ òsì júwe ilé fún àwọn olórí banki kan, kéde olórí tuntun

Aworan Ileese CBN

Oríṣun àwòrán, Others

Ajọ banki apapọ lorilẹede Naijiria ti kede pe ki awọn ọga banki Titan Trust, Union, Keystone ati Polaris lọ rọọkun ni ile.

Bakan naa ni wọn kede awọn olori tuntun fun banki naa.

Ninu atẹjade tí Agbẹnusọ ajọ naa, Sidi Hakama fi lede kede orukọ awọn olori tuntun naa.

Yetunde Oni, Obinrin akọkọ to jẹ Ọga fun ileeṣẹ Banki Standard Chartered ni orilẹede Sierra Leone di Ọga fun ileeṣẹ Banki Union.

Hassan Imam di Ọga fun ileeṣẹ Banki Keystone.

Lawal Mudathir Omokayode Akintola di Ọga fun ileeṣẹ Banki Polaris.

Ajọ banki apapọ lorilẹede Naijiria salaye pe igbesẹ lati yọ awọn Ọga tẹlẹ se koko lẹyin ti awọn Banki naa ko lati tẹle ofin ati ilana ti iwe ofin ti Banks and Others Financial Institutions Act 2020.

Igbesẹ yii waye lẹyin ipade ti awọn ọga banki naa se pẹlu igbakeji gomima ajọ banki apapọ, Phillip Ikeazor pẹlu awọn igbakeji gomina mẹta mii, Emem Usoro, Muhammad Dattijo ati Bala Bello niluu Abuja.

Awọn igbakeji Gomina lo lewaju igbimọ ẹlẹni mẹrin ti wọn gbe idajọ kalẹ lẹyin ipade ọgbọn isẹju pẹlu awọn Ọga banki naa

Saaju ni Aarẹ Tinubu yan oniwadii kan, Jim Obazee, ẹni to n ransẹ pe awọn Ọga ileeṣẹ Banki Titan Trust sugbọn ti wọn kọ lati farahan

CBN wa rọ awọn onibara awọn banki yii lati ma se foya nítorí ko sì nnkan ti yoo sẹlẹ si owo wọn to wa ni ipamọ.