Ìjọba Ògùn fẹ́ẹ́ gbin igi mílíọ̀nù méjì ní 2024

Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, @Dapo Abiodun

Ko din ni miliọnu meji igi oko ti ijọba ipinlẹ Ogun n foju sun lati gbin ki ọdun 2024 yii too pari.

Kọmiṣọnna fun ọrọ Igbo ọba nipinlẹ Ogun, Taiwo Oludọtun, lo sọ eyi di mimọ l’Ọjọruu ọsẹ yii, lọfiisi Gomina Dapọ Abiọdun to wa l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta.

Oludọtun sọ pe awọn nnkan eelo bii agolo ti wọn fi n wọn omi si irugbin,(Watering cans) kẹkẹ (wheelbarrow), paanu ti wọn fi n ru yẹpẹ (Headpan) ati eso igi miliọnu meji ti wọn yoo gbin lawọn nilo fun iṣẹ naa.

O ni gbogbo rẹ lo ti wa nilẹ, awọn yoo si ri i pe ẹnikẹni ko huwa to tapa sofin fun aṣeyọri erongba yii.

‘’Asiko nnkan gbingbin lọdun tuntun ti n sunmọ, a si ti n gbaradi lati gbin igi oko ti ko din ni miliọnu meji’

Miliọnu kan la fojusun lọdun to kọja, ṣugbọn o pada ju bẹẹ lọ ta a gbin pẹlu atilẹyin awọn eeyan ta a ni’

Oludọtun kilọ fawọn to n gegi nigbo ọba laigbaṣẹ, atawọn ti wọn n wọbẹ lẹyin aago mẹfa irọlẹ lati ma ṣe bẹẹ mọ.

O ni ijọba yoo fọwọ ofin mu ẹni to ba tapa sofin to de igi gige nigbo ọba.