Wo àwọn orílẹ̀-èdè 45 tí o lè wọ̀ láì gba ‘Visa’ gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Naijiria lọ́dún 2024-HPI

Oríṣun àwòrán, @NigeriaStories
Ajọ Henley Passport Index, HPI, ti kede awọn iwe irinna awọn orilẹ-ede to lagbara julọ lagbaye.
Ninu atẹjade kan loju opo ayelujara rẹ ni HPI ti kede pe ipo karundinlọgọrun un ni iwe irinna Naijiria wa lara awọn iwe irinna to lagbara ju lagbaye.
Eyii to n tumọ si pe awọn ọmọ Naijiria le fi iwe irinna wọn wọ orilẹ-ede marundinlaadọta lagbaye lai kọkọ gba fisa.
Ajọ wo ni HPI?
HPI ni ajọ to maa n woye bi awọn iwe irinna orilẹ-ede ṣe lagbara si latari iye orilẹ-ede ti awọn to ba ni iwe irinna rẹ lọwọ le wọ lai kọkọ gba fisa.
Atẹjade HPI da lori awọn iroyin to n jade lati ọdọ ajọ International Air Transport Association (IATA), eyii to n ṣakojọpọ bi awọn eeyan ṣe n rinriajo lati orilẹ-ede kan si omiran si.
HPI fi Naijiria si ipo karundinlọgọrun un laarin orilẹ-ede mẹrinlelọgọrun un to kede.
Lara awọn orilẹ-ede ti iwe irinna wọn lagbara ju ti Naijiria ni Afrika ni Ghana, Guinea, Kenya, Lesotho, Morroco, Benin Republic ati Namibia wa.
Eyii ko ṣẹyin bi wọn ṣe wa ni ipo 76th, 83rd, 67th, 65th, 71st, 79th ati 65th gẹgẹ bii atẹjade HPI.
Iwọnyii ni awọn orilẹ-ede ti iwe irinna Naijiria le wọ lai kọkọ gba fisa
1. Barbados
2. Benin
3. Burkina Faso
4. Burundi
5. Cambodia
6. Cameroon
7. Cape Verde Islands
8. Chad
9. Comoro Islands
10. Cook Islands
11. Cote d’Ivoire
12. Djibouti
13. Dominican Republic
14. Fiji
15. Ghana
16. Guinea
17. Guinea-Bissau
18. Haiti
19. Iran
20. Kenya
21. Kiribati
22. Lebanon
23. Liberia
24. Madagascar
25. Maldives
26. Mali
27. Mauritiana
28. Mauritius
29. Micronesia
30. Montserrat
31. Mozambique
32. Niger
33. Niue
34. Palau Islands
35. Rwanda
36. Samoa
37. Senegal
38. Sierra Leone
39. Somalia
40. St. Kitts and Nevis
41. The Gambia
42. Timor-Leste
43. Togo
44. Tuvalu
45. Vanuatu














