Wo bí Ààrẹ Tinubu àtàwọn gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Osun, Kwara àti Eko ṣe ṣe ayẹyẹ ìrántí àwọn ológun

Oríṣun àwòrán, Nigeria Army/ Lagos governor's office
Ayẹyẹyẹ iranti awọn ologun to ṣubu loju ogun ti waye kaakiri Naijiria lonii ọjọ karundinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2024.
Oniruru ọna ni awọn ologun naa fi ṣe iranti awọn akẹgbẹ wọn to ṣubu loju ogun.
Ẹsẹ̀ ogbero loni ni ibi asakagba ayẹyẹ iranti awọn ọmọ ogun to sun loju ija eyi to waye loni ni ilu ilorin olu ilu ipinle Kwara.
Eto na to bẹrẹ Lago mẹsan owurọ oni ni budo ìgba fẹ ati inaju (Kwara Park)
Ninu ọrọ rẹ ni ibi eto na , alaga ẹgbẹ awọn ọmọ Ogun toti fẹyin tí lẹnu ise ni ilẹwa ẹ ka tí ipinle Kwara Major General abdukadir anigiobi kan sara sawọn ọmọ ogun lori ipa takun takun ti wọn ko ni ilẹ Naijiria, pẹlu alaye pe awọn ọmọ ogun fira wọn ji fun ìdurore ilẹ Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army
Ààrẹ Bola Tinubu gbé òdòdò iranti sílẹ̀, ó sì ṣi àwọn ẹyẹ funfun sílẹ̀, eyii to n ṣàpèjúwe àlàáfíà àti iṣọkan orile-ede Naijiria.
Lára àwọn tí wọ́n jọ gbé òdodo ìrántí náà ni mínísítà fún ìlú Abuja, Nyemson Wike, adari àwọn ọlọ́paa, Kayode Egbetokun, adarí ile ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Godswil Akpabio, adarí ilê ìgbìmọ̀ aṣòfin kékeré, Tajudeen Abass, adarí ikọ̀ ọmọ ogun Naijiria, ọgagun Taoreed Lagbaja.
Abuja

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army
Adarí ikọ̀ aláàbò ni Nàìjíríà, ọgagun Christopher Musa ti rọ àwọn ọmọ ogún láti má ṣe káàárẹ̀ nípa gbígbógun ti àwọn adunkokomọni àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ láti rí pé àlàáfíà ni Nàìjíríà.
Gbagede ayẹyẹ ìrántí ikọ ọmọogun ọ̀hún tó wáyé ní Eagles Square, nílùú Abùjá, níbí tí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu àti àwọn ènìyàn pàtàkì ló wà lo ti sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army
Kwara
Ni ipinlẹ Kwara, ayẹwo ilera ọfẹ ati itọju ni awọn ologun naa fi ṣe ayẹyẹ ọhun, nigba ti awọn mii si yan fanda.
Awọn aworan bi ayẹyẹ iranti awọn oogun naa ṣe lọ kaakiri ilẹ Yoruba ree.

Oríṣun àwòrán, bbc
Lasiko ton sọrọ ni ibi eto na akọwe ẹgbẹ awọn ọmọ ogun toti fẹyinti ni Ipinlẹ Kwara Conneli Garuba Lawal ni ọdọọdun leto ayajọ awọn ọmọ ogun ma n waye lati fi mọn riri ipa awọn ọmọ ogun ni idi alafia ati idagbasoke eto abo ilẹ Nigeria.
Ọwa parọwa si ijọba lati tẹ siwaju mimun aye gbẹ dẹmunkẹ fawon ologun.
Ninu ọrọ tiẹ, Gomina Ipinlẹ Kwara Abduraman Abdurasaq ni ko yẹ ki iku awọn ọmọ ogun toti sun loju ija jasi lasan,

Oríṣun àwòrán, Abdulrahman Abdulrazaq
O sọ bi otise pataki to lati mọ̀ riri àwọn ọmọ ogun ilẹ wa fun ipa ti wọn ti ko lori alafia ilẹ Nigeria ati ọrọ eto abo ilẹ wa.
Asoju Ẹmir Ilọrin ni ibi eto na, Yal sheki abduraman Kelani amina ni titi lai ni ilẹ Naijiria yio mon riri awọn ọmọ ologun ti wọn ti fẹmi wọn lelẹ nitori alafia ilẹ Nigeria.

Oríṣun àwòrán, bbc
Lara ohun to waye ni ibi eto nani yiyan bi ologun eyi to sakojọpọ awọn ọmọ ogun, pipin ẹbun fawọn opo ti wọn jẹ iyawo awọn ọmọ ogun toti dologbe ati eto ayẹwo ilera pẹlu itọju ọfẹ

Oríṣun àwòrán, bbc
Ipinlẹ Osun: Ọba tó bá jẹ́ tí ìlú fí dara, ọmọ aráyé kó ní gbàgbé rẹ

Oríṣun àwòrán, bbc
Peter Oladipo ẹni to jẹ Alaga fun awọn Ajagun fẹyinti nipinlẹ Osun, ti sọ ninu ọrọ pe, Ọba to ba jẹ ti ilu fi dara ọmọ araye ko ní gbagbe rẹ, ọrọ yi lo waye ni akoko ti BBC NEWS YORUBA ń fi ọrọ jomi toro ọrọ pẹlu wọn.
Ajagun fẹyinti Peter Oladipo tun tesiwaju ninu ọrọ pe, Gomina Aregbesola se daada ni akoko ìjọba rẹ.
Ọkọ ti Gomina Aregbesola ra fun wa lasiko ìjọba rẹ na lo wa lọwọ wa, ti a si ti kowe si ìjọba Gomina Oyetola lati bawa ra omiran, ti a ko si ri ohun kankan lati ọwọ ìjọba Gomina Oyetola.
Ajagun fẹyinti Peter Oladipo tun fi kun ọrọ rẹ pe, Gomina Ademola Adeleke fun awọn ajagun fẹyinti l'osun ni Milionu Marun nera.
Owo na ko to fun awa ajagun fẹyinti pẹlu awọn to wa lọfisi ti a fun ni owo osu rara.

Oríṣun àwòrán, bbc
Gomina Ademola Adeleke ti ki gbogbo awọn akọni to ti subu loju ogun ati awọn ti o ti jagun fẹyinti.
Bakan naa ni Gomina Ademola Adeleke ti sọ pe, oun yoo mu kẹrin ko gbẹkẹ awọn ajagun fẹyinti ati iyawo awọn akọni to ti subu loju ogun.
Gomina Ademola Adeleke bere fun alafia ati eto abo to peye daada ni ipinle Osun.
Gomina Ademola Adeleke tun fi kun ọrọ pe, oun bere fun ifowosowopo awọn ologun pẹlu awọn osisẹ alabo to ku lati jẹ ki eto abo to peye ko wa nipinlẹ Osun.

Oríṣun àwòrán, bbc

Oríṣun àwòrán, bbc
Ondo: Ìjọba ṣètò ẹ̀yáwó ₦30M fún àwọn opó ológun 66
Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa, ti kede pe ijọba ipinlẹ naa yoo tẹsiwaju nipa pinpin ọgbọn miliọnu naira fun awọn opo ti ọkọ wọn padanu ẹmi gẹgẹ bi ọmọgun ilẹ Naijiria.
Aiyedatiwa lo sọ eleyi nibi ayajọ ọjọ ayẹsi awọn ologun ati iranti awọn ologun to ti fẹyin atawọn to ṣubu loju ija.
Gomina Aiyedatiwa to fun awọn opo naa ni iwe sọwedowo nibi ayẹyẹ naa wi pe ijọba oun yoo tẹsiwaju lati maa mu aye dẹrun fawọn opo ti ọkọ wọn fi ẹmi wọn jin fun Naijiria.

Gomina naa wi pe “eto ẹyawo ti ko ni ele kankan lori taa ṣe fun awọn opo awọn akọni wa jẹ eto pataki fun ijọba yii.
“A ṣe eyi lati ṣe atilẹyin fun iṣẹ wọn ki wọn lee tọju ara wọn atawọn to gbara le wọn.
“Lọdun to kọja, ọpọ awọn opo lo jẹ anfani yii, ti a si ti ṣeto ọgbọn miliọnu naira miran fun wọn lọdun yii.
“A mọ oniruuru ohun tawọn eyan n sọ nipa ẹyawo yii, ati bi awọn opo kan ṣe kọ lati da owo naa pada. A n fi daa yin loju pe a o maa pese owo yii lọdọọdun, amọ a bẹ yin ki awọn to ba ti jẹ anfani ẹyawo naa o maa daa pada ki awọn miran o tun lee jẹ anfanii rẹ.”

Aiyedati gboriyin fun awọn ajagunfẹyinti to wa nipinlẹ naa fun ipa ti wọn n ko ninu idaabobo ipinlẹ ọhun.
‘Eto ẹyawo yii ni mo fi n tọju awọn ọmọ mi’
Ọkan lara awọn to jẹ anfani ẹyawo ọhun, Hadiza Mohammed, to wa lati 32 Artillery Brigade dupẹ pupọ fun ijọba ipinlẹ Ondo fun eto naa.
Hadiza wi pe “ko rọrun lati maa da tọju ọmọ mẹrin lai lọkọ. Ogo Ọlọrun la fi n gb'aye.
“O ṣoro fawọn miran to lọkọ, ka too sọ ti ẹni ti ko ni, amọ o dami loju pe owo yii yo nipa rere lori aye wa ati tawọn ọmọ wa, paapaa julọ owo ileẹkọ awọn ọmọ.
“Oṣu kẹta, ọdun 2021 ni ọkọ mi, Mohammed Ali, papoda ti mo si ti n da tọju awọn ọmọ lati igba naa.
“Ọdun meji ṣẹyin ni mo bẹrẹ si nii jẹ anfani ẹyawo yii, mo si ni okoowo kekere ti mo n ṣe.”
Ipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, Governor's office

Oríṣun àwòrán, Governor's office

Oríṣun àwòrán, Governor's office

Oríṣun àwòrán, Governor's office
Òní ni àyájọ́ ìrántí àwọn ọmọ ogun to ṣubu lójú ogun ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Others
Gbogbo ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Kìíní ọdún ni àyájọ́ ìrántí àwọn ọmọ ogun tó ṣubú lójú ogun ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ọjọ́ yìí ni ìjọba Nàìjíríà yà sọ̀tọ̀ láti máa ṣe ìrántí àwọn ọmọ ogun tó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ogun kan tàbí òmíràn lásìkò tí wọ́n ń dá ààbò bo ilẹ̀ bàbá wọn.
Lẹ́yìn ogun àgbàyé àkọ́kọ́, ọjọ́ Kọkànlá oṣù Kọkànlá ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń ṣe àyàjọ́ yìí.
Àmọ́ lẹ́yìn ogun abẹ́lé tó wáyé ní Nàìjíríà, tí àwọn ọmọ ogun Biafra juwọ́ lẹ̀ fún ìjọba Nàìjíríà ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Kìíní ọdún 1970 ni àyípadà ti bá àyájọ́ náà.
Láti ìgbà náà ni wọ́n ti máa ń ṣe àyájọ́ ọjọ́ yìí ni ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Kìíní ọdọọdún.
Káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀ ni ayẹyẹ náà ti máa ń wáyé láti fi bu ọlá fún àwọn ọmọ ogun tó pàdánù ẹ̀mí wọn lójú ogun.
Bákan náà ni wọ́n máa fi ń ṣe kóríyá fún àwọn tó ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ àtàwọn ọmọ ogun tó ti dàgbà lẹ́nu















