Ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì mú ẹ̀mí èèyàn 33 lọ ní Colombia

Oríṣun àwòrán, reuters
Iye eeyan to ti jade laye latari iṣẹlẹ ilẹ riri to waye ni Ariwa Colombia ti pe mẹtalelọgbọn bayii.
Igbakeji Aarẹ orilẹ-ede naa ti sọ fun awọn akọroyin pe ọmọde lo pọ ju ninu awọn to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.
Yatọ si awọn to ku, eeyan mọkandinlogun mii lo farapa, amọ wọn ti n gba itọju.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye
Ṣaaju ni ilẹ riri kan ti kọkọ waye, eyii to di oju ọna ti awọn araalu n gba laarin ilu Medellín ati Quibdo, to si mu ki ọpọ eeyan maa sun sinu ọkọ ayọkẹlẹ wọn.
Lẹyin naa ni iṣẹlẹ ilẹ riri mii waye, eyii to bo ori awọn eeyan ọhun ati ọkọ wọn mọlẹ.
Aarẹ Colombia, Gustavo Preto, ti sọ pe gbogbo iranlọwọ ti awọn araalu nilo lẹyin iṣẹlẹ naa ni ijọba oun yo pese fun wọn.
Ọkan lara awọn to moribọ ninu iṣẹlẹ ọhun ṣalaye fun awọn akọroyin pe nnkan bi ọgọta eeyan lo fi ara pamọ sinu ile kan ṣaaju iṣẹlẹ naa.
Bo tilẹ jẹ pe ko fẹ darukọ ara rẹ, o sọ fun ileeṣe iroyin abẹle El Tiempo pe oun loun n fun awọn eeyan naa ni dodo ati ata dindin lasiko ti ojo bẹrẹ, ki ilẹ to bẹrẹ si n ya.
O ni laarin iṣẹju aaya ni ilẹ ọhun ya, to si gbe ile naa ati ọpọlọpọ ọkọ lọ.
Igbakeji Aarẹ Colombia, Francia Márquez Mina, sọ loju opo X rẹ pe ọpọ awọn adoola ẹmi, ọlọpaa, atawọn ọmọ ogun lo ti lọ sagbegbe Choco lati ran awọn eeyan lọwọ nibẹ.
Iṣẹlẹ naa waye lẹyin ojo arọrọda to waye lọjọ Ẹti ati ọjọ Abamẹta lagbegbe Choco, eyii ti ko jina si alagbalugbu omi omi okun Pacific Ocean.














