Wo ìdí tí òkú sínsin fi di ìṣòro fún àwọn Mùsùlùmí lórílẹ̀èdè Japan

Awọn Musulumi

Oríṣun àwòrán, Getty

Idaluu niṣelu, ba a si ti n ṣe nilẹ yii, eewọ ibo mii ni. Eyi lo fa a tawọn Musulumi ti wọn n gbe lorilẹ-ede Japan, nibi ti wọn ti maa n dana sun oku tiwọn, ṣe n koju iṣoro ati ribi sinku nilana Islam, ati bi oku ṣe n pẹ nilẹ ju aṣẹ ẹsin wọn lọ.

Iwọn perete lawọn Musulumi ti wọn wa ni Japan, wọn ko ju ẹgbẹrun lọna igba 200,000) eeyan lọ ninu ọgọfa miliọnu (120,000,000) eeyan to n gbe loril-ede naa.

Ofin ẹsin Buddhism ati Shinto ti wọn n ṣe ni Japan ni lati dana sun oku, nigba ti ẹsin Islam lodi si eyi. Islam ni ki wọn sin oku sinu ilẹ laipẹ rara lẹyin to ba jade laye ni.

‘Maili rẹpẹtẹ la maa n ru oku wa lọ ka too ri wọn sin ọjọ yoo si ti lọ’ ‘

Mosalaasi nla

Ọkunrin kan, Tahir Abass Khan to jẹ Musulumi to si ti n gbe Japan lati 2001, fẹdun ọkan ṣalaye pe, ‘’Oore ikẹyin ti mo le ṣe fun ọmọ iya mi ninu ẹsin, tabi ọrẹ mi nigba to ba ku ni ki n filẹ bo o laṣiiri.

‘’Ki i ṣe pe ki n dana sun un. Bi mi o ba le sin in sinu ilẹ, inu mi ko le dun rara, emi naa ko le maa fayọ gbele aye lọ’’

Abass Khan, ọmọ orilẹ-ede Pakistan to ti di profẹsọ, iyẹn Ọjọgbọn, to si ti di ọmọ Japan naa nitori ọdun pipẹ to ti n gbe nibẹ, tẹsiwaju, pe oun da ajọ kan silẹ fawọn Musulumi, eyi torukọ rẹ n jẹ Beppu Muslim Association.

‘Ohun ti yoo ṣelẹ si mi ti mo ba ku kọ lo n ṣe mi, irora tawọn yooku mi yoo jẹ lo n ba mi lọkan jẹ’

Awon obinrin Musulumi to n kirun

Ọjọgbọn Khan yii sọ pe inira ti yoo koju awọn eeyan ti wọn ba dana sun ni ohun to n ba oun lọkan jẹ ju, ki i ṣe toun alara.

O ni mọṣalaaṣi akọkọ tawọn kọ wa ni Oita, ni Guusu Erekuṣu Kyushu, ni 2009, ṣugbọn igbiyanju ṣi n lọ lati faaye silẹ fun itẹ oku musulumi. O ni ọdun kẹwaa ree toun ti wa lẹnu ẹ.

Ẹgbẹrun kan kilomita la lọ nigba ta a fẹẹ sinku iyawo mi

ọ̀nà jìn réré

Ọdun 2004 ni Musulumi kan, Ọmọwe Mohammed Iqbal Khan, bẹrẹ si i gbe Japan pẹlu iyawo rẹ.

Obinrin naa ku ni 2009, idaamu si de nigba ti wọn ko le sinku rẹ si Japan, afi ki wọn rin irin ẹgbẹrun kan kilomita.

" A gbe e sinu apoti kekere kan, a kọri si Yamanashi ninu mọto. Ẹgbẹrun kan kilomita ni.

O wu mi ki n duro tiyawo mi ṣugbọn ko ṣee ṣe.

‘A ra ilẹ lati sinku si, awọn ara adugbo sọ pe a fẹe ba omi tawọn n mu jẹ ni’

Itẹ oku

Oríṣun àwòrán, Getty

Ọmọwe Iqbal tẹsiwaju pe awọn Musulumi ra ilẹ kan sitosi ilẹ tawọn Kristẹni maa n sinku si ni Beppu. O lawọn to jẹ alamulegbe awọn ko sọrọ o, wọn fara mọ ọn.

Awọn ara adugbo naa lo ni wọn ko gba, ti wọn sọ pe ẹni to ba n sinku silẹ fẹẹ ba omi tilu n mu jẹ ni. Yoo si koba eyi tawọn fi n ṣọgbin naa.

Ẹni to ba ni Kansa tabi aisan aṣekupani mi-in ninu wa yoo tete pada siluu rẹ lati lọọ ku sibẹ ni

Nigba ti ko si àbujá kankan lọrun ọpẹ fun iṣoro yii, Ọmọwe Khan sọ pe ati gba iwe pe awọn n gbe oku lọ sorilẹ-ede mi-in ki i ya, wahala rẹ si pọ. Iyẹn lo fi jẹ pe ẹni to ba ni Kansa tabi aisan aṣekupani mi-in ninu awọn yoo maa pada sorilẹ-ede rẹ lati lọọ ku sibẹ ni.

Kaka ki wọn ku silẹ ajeji ti isinku ti jẹ iṣoro.

Ọna abayọ

Ọmọwe Khan sọ fun BBC pe itẹ oku mẹtala lo wa ni Japan, pẹlu tuntun kan ti wọn ṣẹsẹ kọ si Hiroshima, ti ko ju wakati mẹta lọ teeyan yoo fi wa mọto debẹ.

O ni awọn alaṣẹ agbegbe ibilẹ ti faaye silẹ lati sinku si, mọkandinlọgọrin( 79) ni wọn si yọ silẹ fawọn musulumi.

Ohun to jẹ iṣoro bayii bo ṣe wi ni pe wọn ki i fun awọn niwe aṣe ati sinku .

A ṣetan lati sanwo funjọba, awa naa ko sọ pe ọfẹ la fẹ.

Ki wọn gbowo ki wọn si fun wa laṣẹ isinku. Abi ki wọn kọ itẹ oku ẹlẹsin gbogbo kaakiri Japan, ki kaluku maa gbe oku rẹ lọ sibi to ba wu u nibẹ.

Awa o ni i dana sun oku labẹẹ bo ṣe wu ko ri

Ọmọwe Khan sọ pe ko sohun to le ṣẹlẹ ti Musulumi yoo fi dana sun oku.

O lawọn yoo yaa fi kun igbiyanju awọn ni, ilẹ loku awọn yoo maa sun, ko ni i jẹ didana sun bii oku ẹlẹsin Buddhism.