Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ pásítọ̀ ẹni ọdún 43 tó bá ọmọdé lòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Ogun State Police
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe oun ti fi ṣikun ofin mu pasitọ ẹni ọdun mẹtalelogoji kan, Clinton John, lagbegbe Agbado, nipinlẹ naa.
Ọlọpaa mu pasitọ ọhun lori ẹsun pe o fi ipa ba ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan lopọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa nipinlẹ Ogun, Omolola Odutola, lo fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade kan to fi sọwọ si awọn akọ royin.
Odutola sọ pe awọn mọlẹbi ọmọdebinrin naa to n gbe lagbegbe Giwa Agbado lo fi ọrọ naa lọ ni agọ ọlọpaa to wa lagbegbe Agbado.
O ni “Awọn mọlẹbi naa sọ pe awọn ti n ṣetọju ọmọ naa lẹnu ọjọ mẹta yii fun awọn to jọ mọ ibalopọ, o si n wu iwa bii ẹni ti ẹru n ba, eyii to mu ki wọn fura si pe o ti n ni ibalopọ.”
“Amọ o fi orukọ ẹni to ba ni ibalopọ pamọ, ṣugbọn lẹyin ti wọn tẹ ẹ ninu daadaa lo jẹwọ pe pasitọ John, ti ijọ Mega Healing Ministry, lo ti n ba oun lopọ lati inu oṣu Kọkanla, ọdun 2022.”
“Ọmọ naa tun sọ pe pasitọ ọhun dunkoko pe oun yoo ṣekupa oun ti oun ba le sọrọ nipa ibalopọ naa fun ẹnikẹni.”
Agbẹnusọ ọlọpaa ni afurasi ọhun ti jẹwọ ni agọ awọn pe lootọ ni oun fi ọwọ kan ọmọde naa lọna ti ko tọ.
O pari ọrọ rẹ pe wọn ti ṣe ayẹwo ilera ọmọdebinrin naa, o si ti n gba itọju lọwọ.
Ẹwẹ, o fi kun pe wọn ti tare afurasi si ẹka CID to wa niluu Abeokuta fun iwadii to peye lori ọrọ ọhun.














