Wọ́n bá òku ọmọ ọdún kan nínú kàǹga lẹ́yìn ọjọ́ kẹ́ta tí wọ́n ti ń wá a nípìnlẹ̀ Ògùn

Ọjọ kẹfa, oṣu kin-in-ni , ọdun 2024 yii ni omọdebinrin kan, Janet Ajayi, ọmọ ọdun kan, deedee edi awati niwaju ile wọn n’Itori, ijọba ibilẹ Ewekoro nipinlẹ Ogun.
Ọjọ kẹta iṣẹlẹ naa ni wọn ba oku ẹ ninu kanga kan nile keji.
Alaye ti Iya Janet ṣe fawọn ọlọpaa ni pe ọmọ naa n ṣere niwaju ita ni, oun si wọle lati mu aṣọ ti yoo wọ fun un.
O nigba toun jade sita pada loun ko ri ọmọ oun mọ.
Iya Janet sọ pe awọn wa a titi, awọn ko ri i. Ọjọ kẹta lawọn ri oku rẹ to lefoo soju omi ninu kanga to wa nilee keji.
Eeyan mẹta dero ileewosan nile ti wọn ti ri oku Janet
SP Odutọla fidi ẹ mulẹ, pe eeyan mẹta ninu awọn to n gbele onikannga ti wọn ti ri oku Janet lo fara ṣeṣe nigba tawọn eeyan tinu n bi yabo wọn.
Ọrọ naa di rogbodiyan gẹgẹ bi Alukoro ṣe wi, wọn kọlu awọn eeyan ninu ile ti wọn ti ri oku ọmọ naa. Ileewosan ni wọn si sare gbe awọn mẹta to farapa lọ.
‘’ A ko mu ẹnikẹni lori iṣẹlẹ yii, awọn ẹbi ọmọ naa kọ lati ṣayẹwo oku rẹ, wọn ti sin in’
Alukoro Odutọla tun ṣalaye pe awọn ko mu ẹnikẹni gẹgẹ bii afurasi ninu iṣẹlẹ naa, nitori awọn ẹbi ọmọ to ku ko tẹle imọran ọlọpaa lati ṣayẹwo oku rẹ.
Ai ṣe ayẹwo ko le jẹ ki wọn fidi iku to pa Janet mulẹ, ko si ṣee ṣe lati mu ẹnikẹni ni Odutọla sọ.














