Ṣé lóòtọ́ ni CAF tún ní pé kí Kanga wá sọ ìdí tí Ìyá rẹ̀ fi kú lọ́dun 1986, tí wọ́n sì bí i lọ́dun 1990?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Bayii ti idije AFCON tun gbode ni orisiirisii iroyin n jade lori ayelujara.

Ọkan lara iru iroyin to n jad eyii ni pe CAF tun ranse pe Kanga Kaku pe ko wa ṣalaye nipa aiṣedeede to wa ninu ọjọ ori rẹ.

Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ sẹyin?

Saaju asiko yii ni Ajọ ere bọọlu ni ilẹ Afrika, CAF tí ransẹ pe agbabọọlu orilẹede Gabon, Guelor Kanga Kaku koju igbimọ oniwadii CAF.

CAF ni kí Kanga wa salaye idi ti iya rẹ fi ku lọdun 1986 sugbọn o bi ni lọdun 1990.

Saaju lọdun 2021 ni orilẹede DR Congo sọ pe awọn yoo morile ile ẹjọ lati se ọfin toto boya Kanga ni ẹtọ lati gba bọọlu fun Gabon pẹlu ọjọ orí rẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ajọ agbabọọlu Congo gbagbọ pe Kanga parọ ọjọ orí nigba to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu GBI ni Gabon.

Gẹgẹ bii alaye wọn, agbabọọlu naa ko le jẹ ọmọ ọdun 1990 ti iya rẹ ba jade laye lọdun 1986.

Kanga ẹni to ti gba ìfẹsẹwọnsẹ mẹrindinlaadọta fun orilẹede Gabon

CAF ti wa kede síta awọn yoo bẹrẹ iwadi lati mọ boya Kanga parọ ọjọ gẹgẹ bii ẹsun ti wọn fi kan.

Awọn iwe ẹri Kanga fihan pe Kanga jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlọgọrin sugbọn to jẹ pe o safihan ara rẹ gẹgẹ ọmọ ọdun mejilelọgbọn.

Kini o n ṣẹlẹ bayii?

Iroyin sọ pe ajọ ere bọọlu CAF ti yanju ọrọ naa ti o si fidie mulẹ pe iroyin to ti pẹ ti wọn ti yanju ni awọn mii tun lọ gbe sita bayii.

Ati pe eyi ko ni nkankan ṣe pẹlu idije bọọlu ilẹ Adulawọ AFCON 2023 to bẹrẹ yii.