Jẹ́ kí gbogbo ayé ó ríi pé o gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ ní tòótọ́ - Afenifere rọ Tinubu

Aworan Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu/Facebook

Ẹgbẹ Afẹnifẹre lo ti ṣe atunwi ipinnu rẹ lati ṣe atilẹyin fun ijọba to wa lori aleefa lorilẹede Naijiria ninu igbogun ti iwa ibajẹ ati iwa jẹgudujẹra.

Ẹgbẹ naa sọ ọrọ yii ninu atẹjade kan ti akọwe iṣeto, Kole Omololu, fi sita.

Ninu atẹjade naa ni wọn ti rọ Aarẹ Bola Tinubu lati fihan gbangba ni tootọ pe oun ṣetan lati dẹkun iwa jẹgudujẹra ni Naijiria.

Afẹnifẹre lo ni ki Tinubu o rii pe iwadii to jinlẹ waye lori awọn ẹsun ikowojẹ to wa nileeṣẹ eto ẹlẹyinju aanu ati pipa oṣi rẹ, ki eyi o si waye lai si agabangebe kankan.

Ẹgbẹ naa sọ ninu atẹjade ọhun pe: “gẹgẹ bi ẹgbẹ to ni ifarajin fun itẹsiwaju ati iduroore ilẹ yii, wọn ni awọn ti ṣetan lati ṣe atilẹyin fun ijọba lati le gbogun ti iwa ibajẹ.

“Igbagbọ wa ni pe mimu opin ba iwa ibajẹ ni ọpakutẹlẹ ayika ti yoo mu ki idagbasoke ati anfani to dọgba le wa fawọn ọmọ Naijiria.”

Afẹnifẹre wi pe “a rọ Aarẹ Bola Tinubu lati ṣe atunwi ipinnu rẹ ati ijọba to n dari lati mu idagbasoke to lọọrin ba ilẹ Naijiria.

“Gẹgẹ bi aarẹ ati adari gbogbo ajọ ologun nilẹ yii, Tinubu ni lati fihan gbangba pe oun ṣetan lati yanju ohun to n jẹ iwa ibajẹ, leyi to n dena ilọsiwaju orilẹede yii lati ọjọ pipẹ.

“A ni igbagbọ pe aifi aaye gba iwa ibajẹ lo lee mu ki ilẹ yii o tẹsiwaju.

“Pẹlu gbogbo ohun ti a n gbọ nipa ileeṣẹ ẹlẹyinju aanu ati pipa oṣi rẹ lawujọ lẹnu ọjọ mẹta yii, a rọ aarẹ lati rii pe iwadii to kunna waye lori awọn ẹsun naa.

“O di dandan lati ṣe ayẹwo finnifinni lori gbogbo inawo ti ileeṣẹ naa ṣe lati rii boya o bofin mu.”

Ẹgbẹ naa koro oju si lilo biliọnu mẹrin naira lati ṣayẹwo orukọ awọn ti yoo jẹ anfaani eto ileeṣẹ na, ti wọn si beere pe elo gan ni yoo ku lati pin ti wọn ba lo biliọnu mẹrin lati ṣayẹwo orukọ.

Afẹnifẹre wi pe “a ṣe atẹnumọ pataki iwadi yii lai ni ọwọ kan eru ninu ki otitọ o lee fara han.

“Awọn ọmọ orilẹede yii lo fi igbagbọ wọn kọ Aarẹ Tinubu lọrun, to si di dandan ko fidi igbagbọ yii mulẹ nipa jijẹ olootọ ati kiko akoyawọ.”