Mi ò lo ayédèrú ìwé ẹ̀rí, wọ́n fẹ́ bàmí lórúkọ jẹ́ ni o - Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, Facebook
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Lucky Aiyedatiwa tí júwe ẹ̀sùn pé òun yí ìwé ẹ̀rí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí òun lọ gẹ́gẹ́ bí ìbanilórúkọ jẹ́.
Aiyedatiwa ní àwọn tó ń gbé ìròyìn òfégè náà mọ̀ ọ́n-mọ̀ ṣe ni nítorí ètò ìdìbò tó sún mọ́.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ gómìnà Aiyedatiwa, Ebenezer Adeniyan fi síta ní gómìnà ọ̀hún ti sọ pé gbogbo àwọn ìwé ẹ̀rí oun ló wà ní ojútáyé.
Ó ní gbogbo àwọn ìwé ẹ̀rí náà ni òun kó síwájú àjọ tó ń mójútó ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC nígbà tí òun àti Gómìnà àná, Rotimi Akeredolu fẹ́ díje dupò gómìnà lọ́dún 2020.
Ó ní àwọn olóṣèlú kan ni wọ́n ń gbé ìròyìn irọ́ náà kiri lẹ́yìn tí wọ́n gbìyànjú láti ba gómìnà náà lórúkọ jẹ́ lórí ikú Akeredolu àmọ́ tí wọn kò jẹ lọ.
Lucky ṣàlàyé pé ó pọn dandan láti jẹ́ kí àwọn ará ìlú mọ̀ nípa ìgbìyànjú àwọn ènìyàn náà ṣáájú kí ètò ìdìbò tó wáyé.
Ó fi kun pé àwọn ènìyàn ló gbìyànjú láti yọ gómìnà Aiyedatiwa nípò nígbà tó wà ní igbákejì gómìnà ṣùgbọ́n tí kò wá sí ìmúṣẹ.
Ó ní pípèsè ètò ìjọba tó dúró ire fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ondo ló jẹ òun lógún àti pé òun kò ní jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà ṣi àwọn lọ́kàn lórí àwọn nǹkan tí àwọn fẹ́ ṣe fún ará ìlú.
Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kìíní, ọdún 2024 ni ẹgbẹ́ kan, Ondo State Redemption Initiative (OSRI) fẹ̀sùn kan gómìnà Aiyedatiwa pé ó ń lo ayédèrú ìwé ẹ̀rí.
Ẹgbẹ́ OSRI nínú àtẹ̀jáde tí Ààrẹ wọn Adebayo, akọ̀wé ẹgbẹ́ Jide Oriola àti agbenusọ wọn, Sunday Ayeni pawọ́pọ̀ fi síta ní Aiyedatiwa ní òun kẹ́kọ̀ọ́ gboyè Advanced Diploma ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ibadan lọ́dún 2001.
Àtẹ̀jáde náà ní ìwádìí àwọn fi hàn pé ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ibadan kò ì tíì má ṣe Advanced Diploma nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Business Administration lọ́dún 2001 tó ní òun jáde.
Àmọ́ gómìnà Aiyedatiwa ní irọ́ ni àwọn ẹgbẹ́ náà ń pa àti pé kí àwọn ènìyàn má kọbi ara si.















