Ìjọba kéde ṣíṣí afárá 3rd Mainland Bridge padà

Oríṣun àwòrán, Others
Ìjọba àpapọ̀ ti kéde pé àwọn yóò ṣí afárá Third Mainland fún lílò pátápátá ní ọjọ́ Kérin, oṣù Kẹrin ọdún 2024.
Mínísítà fún iṣẹ́ òde, David Umahi ló kéde yìí nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí afárá náà pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ ilé aṣòfin àpapọ̀ lórí iṣẹ́ òde.
Ó ní òun ti pa iléeṣẹ́ tó ń ṣe àtúnṣe ọ̀nà náà láṣẹ láti ṣí ọ̀nà ọ̀hún lórúkọ òun lój;unà àti mú ìdẹ̀kùn bá àwọn èèyàn tó ń lo ọ̀nà ṣáájú kí ààrẹ Tinubu tó wá ṣì.
Ó ṣàlàyé pé iṣẹ́ ọ̀nà oní kìlómítà mọ́kànlá lé ọwọ́ mẹ́jọ náà èyí tí iléeṣẹ́ CCEC ṣe àtúnṣe rẹ̀ ni èròńgbà wà pé bílíọ̀nù mọ́kànlélógún náírà ni àwọn máa kọ́kọ́ ná si àma tó padà jù bẹ́ẹ̀ lọ nítorí àwọn àtúnṣe mìíràn tó wáyé níbẹ̀.
Bákan náà ni kọ́míṣánnà fún ètò ìrìnnà ìpínlẹ̀ Eko, Oluwaseun Osiyemi, fi àtẹ̀jáde síta pe àwọn ti ṣetán láti ṣí afárá náà.
Osiyemi ní àtúnṣe gidi ló wáyé lórí afárá náà fún bí oṣù mélòó tí wọ́n fi ti afárá náà láti ọdún tó kọjá.
Ó ní ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kẹrin ní àwọn máa ṣí afárá náà pátápátá, tí àwọn tó ń lọ, tọ ń bọ̀ yóò sì ní àǹfàní láti máa gba ọ̀nà wọn tó tọ́.
Ó wá dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko fún sùúrù àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn láti ìgbà tí iṣẹ́ àtúnṣe náà ti bẹ̀rẹ̀.
Ẹ ó rántí pé nínú oṣù Kẹwàá, ọdún 2023 ni ìjọba àpapọ̀ kéde pé àwọn máa ti afárá náà fún ìgbà kan ná láti ṣe àwọn àtúnṣe lórí rẹ̀.
Àtúnṣe afárá 3rd Mainland Bridge yóò tẹ̀síwájú fún ọ̀sẹ̀ méje míì ṣùgbọ́n......- Ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Ìjọba àpapọ̀ ti kéde pé àtúnṣe tí wọ́n ń ṣe sí afárá Third Mainland Bridge tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko yóò tẹ̀síwájú láti ọjọ́ Kẹsàn-án oṣù Kìíní ọdún 2024.
Adarí ẹ̀ka tó ń mójútó iṣẹ́ òde, Olukorede Kesha ni ọ̀sẹ̀ méje ni àtúnṣe yóò tún fi wáyé lórí afárá náà, tí wọn yóò sì máa ti ọ̀nà náà fún àwọn ìgbà kan lójúmọ́.
Kesha nínú àtẹ̀jáde tó fi síta ṣàlàyé pé títi ọ̀nà ọ̀hún yóò mú kí àwọn parí iṣẹ́ tí àwọn ń ṣe lórí rẹ̀, èyí tí wọ́n dá dúró lọ́jọ́ Kẹrìnlá oṣù Kejìlá ọdún 2023 nítorí pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ọdún.
Ó ṣàlàyé pé ẹ̀ka Iyana Oworoshoki sí Adeniji Adele ni iṣẹ́ yóò ti wáyé lórí ọ̀nà náà báyìí.
Bákan náà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Eko tún gbé àtẹ̀jáde síta láti fi atọ́nà fún àwọn ènìyàn lórí àwọn ọ̀nà mìíràn tí wọ́n lè gbà nígbà tí iṣẹ́ bá fi ń lọ lórí Third Mainland Bridge.
Kọmíṣọ́nà fún ètò ìrìnnà ìpínlẹ̀ Eko, Oluwaseun Osiyemi nínú àtẹ̀jáde tó fi léde ní àwọn tó bá ń lọ sí Island láti Mainland yóò ní àǹfàní láti ṣe àmúlò afárá náà láti aago méjìlá oru di aago méjìlá ọ̀sán.
Bákan náà ló ní àwọn tó bá ń bọ̀ láti Island lọ sí Mainland yóò ní àǹfàní láti lo afárá náà láti ago méjìlá ọ̀sán di ago méjìlá òru.
Osiyemi rọ àwọn onímọ́tò tó ń lo ọ̀nà yìí láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìrìnnà tí wọ́n yóò máa mójútó lílọ àti bíbọ̀ ọkọ̀ lásìkò yìí.
Ó ní èyí yóò mú àdínkù bá kìràkìtà tí yóò wáyé lásìkò yìí.
Bẹ́ẹ̀ náà ló tún pàrọwà sí àwọn ènìyàn láti lo àwọn ọ̀nà mìíràn tí wọ́n là kalẹ̀ lásìkò tí afárá náà bá wà ní títì.
Àwọn ọ̀nà tí àwọn ènìyàn lè gbà ni Ojota – Ikorodu Road- Funsho Williams Avenue – Eko Bridge-Apogbon-CMS.
Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ tún lè gba Ojota- Ikorodu Road- Jibowu – Yaba- Oyingbo-Iddo- Carter Bridge- CMS, and Gbagada- Anthony- Ikorodu Road- Funsho Williams – Eko Bridge- Apogbon Bridge – CMS.
A ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àtúnṣe afárá Third Mainland láti ọjọ́ kínní, oṣù tó ń bọ̀ – Ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, getty images
Minisita fun iṣe, David Umahi, ti sọ pe ijọba apapọ yoo bẹrẹ atunṣe afara Third Mainland to wa niluu Eko.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, oṣu mẹta gbako ni wọn yoo fi ṣiṣẹ naa, eyii ti yoo bẹrẹ lọjọ kinni, oṣu Kọkanla, ọdun 2023.
Umahi lo sọ ọrọ naa lasiko to n yẹ abẹ afara naa atawọn afara mii wo niluu Eko.
Yatọ si afara Third Mainland, Umahi pẹlu awọn akọṣẹmọṣe amojuẹrọ tun yẹ afara Carter, Independence ati afara Falomo wo niluu Eko yii kan naa.
Umahi tun ṣabẹwo si eti odo Marina, afara Five Cowries to ti n bajẹ lagbagbe Onikan, ko to tun lọ bẹ afara Ijora ati afara Marina wo ni Apapa.
Ninu ọrọ rẹ, gbogbo ori afara Third Mainland naa ni iṣẹ yoo kan.
O ni iṣẹ afara Third Mainland naa ko ni mu inira pupọ ba awọn araalu to n lo afara ọhun nitori ọganjọ oru ati opin ọsẹ lawọn oṣiṣẹ yoo maa ṣiṣẹ nibẹ.
Minista naa sọ pe ọpọlọpọ koto lo wa lori afara ọhun, eyii to nilo ki wọn wu ọda ori rẹ lọna ati le da ọda mii si.
“A maa ṣi awọn ọda to pọ ju lori rẹ ki a le dinku si iwọn milimita meji pere.”
O tẹsiwaju pe aarin aago mejila oru si aago mẹrin idaji ni awọn oṣiṣẹ yoo maa ṣiṣẹ nibẹ.













