Wo ọ̀bítíbitì owó tí ìlú Florida ń san fáwọn obìnrin tó ń dọdẹ ejòlá

Aworan Amy Siewe ati awọn akẹgbẹ rẹ nibi ti wọn ti gbe ejola nla kan lọwọ

Oríṣun àwòrán, Amy Siewe

Ọdẹ ejola ni orukọ ti ọpọ mọ Amy Siewe si ti a si ri nibi to ti n dẹ ọdẹ ejola kan to gun ni iwọn bata ogun to n wa ohun ti yoo gbe hanu.

Lasiko ti yinyin ba n rọ lati sanmọ, oju ọsan ni Amy a maa fi wa awọn ejola yii.

Amọ bo ba di igba ooru, alẹ ni asiko to yan laayo lati maa fi dẹ ọdẹ ejola rẹ.

Iṣẹ to yan laayo yii kii ṣe tori ki o ba ni iwuri pe oun lepa awọn afayafa wọnyi bi kii ṣe pe ko fi daabo bo ayika.

Laarin ibẹrẹ ọdun 1990 ni wọn kọkọ gbe awọn ejola wa lai ilu Burma gẹgẹ bi nkan ọsin lọpọ idile.

Larin ọdun 1996 si 2000, onka iye awọn ejo wọnyi to ti wọ ilẹ America ti sunm ẹgbẹrun mọkandinlọgọrun.

Pupọ awọn ejo yi lo rapala wọ inu igbo nibi ti won a ti maa ri oriṣi ounjẹ bi ekute jẹ.

Siewe sọ pe eeyan kan le maa wa ọkọ lọ ko si ṣe alabapade awọn ejo wọnyi lairotẹlẹ.

Kete to ba ti foju kan wọn, Siewe yoo bọ silẹ ninu ọkọ rẹ ti yoo si gba ori ejo naa mu.

Ati ohun ati awọn to n ba ṣiṣẹ yi, won a maa wa ninu ewu pe awọn ejo yi le fi yin ha wọn ṣugbọn wọn kii ṣe ejo to loro to le pa eeyan.

Siewe nifẹ si iṣẹ yi to si ni igbakugba toun ba ri ejo kankan mu , ayipada nla lo n mu ba ayika .

Awọn ọdẹ ejola

Ọdun mẹrin ni Siewe ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi ẹni to n ba wọn gbe awọn ejola kuro ninu omi to wa layika Guusu Florida.

Owo wakati wakati lo n gba ti iṣiro rẹ si jẹ bi $13 (£10.22) si $18 (£14.15).

Ibi to ba ti n ṣiṣe ati iye wakati to lo ni yoo tọka iye owo ti yoo mu lọ sile.

To ba mu ejola ti ko to iwọn ẹṣẹ bata mẹrin, yoo gba aadọta dọla.

Yoo si tun gba dọla marundinlọgun ni isiro odiwọn ẹsẹ bata kọọkan ejo to ba ri mu.

To ba tun wa sawari isa ejola ti ejola wa nibẹ, wọn yoo san igba dọla fun.

E o ri pe obitibiti owo lo n gba lori iṣẹ to n ṣe yi!

Aworan awọn to n kopa ninu idije ẹni ba le mu ejola lọdun 2022 python challenge

Oríṣun àwòrán, South Florida Water Management District

Tori pe awọn ejola jẹ ẹrankọ ti ofin de, awọn eeyan ko le gbe wọn sinu ọkọ laaye.

Awọn to n mu ejola ni Florida ti gba idanilẹkọ to peye nipa fifi oriṣi ibọn lati fi pa ejola naa.

Eto ejola mimu yi ti wọn gbe kalẹ lọdun 2017 ti ja si pe wọn ti pa to ejola to sunmọ ẹgbẹrun mẹjọ.

Pupọ awọn ejola yi gun niwọn ti ko to iwọn ẹsẹ bata mẹrin botilẹ jẹ wi pe wọn ri awọn mẹtadinlogun kan mu ti wọn gun to iwọn ẹsẹ bata mẹtadinlogun ati mẹrindinlogun.

Owo mii tun wa ti Siewe a maa pa sapo nipa tita awọ ejo wọnyii.

Amọ o pada ri wipe awọn arinrinajo inaju a maa san owo to ju bẹẹ lọ to ba mu wọn rinrin ọdẹ ejola.

Fun idi eyi, a le ka kun awọn eeyan diẹ to ṣe pe idi ejola yi ni owo rẹ sodo mọ.

Ṣiṣe akoba fun ayika

Igbagbọ ni pe awọn to n ṣowo eranko lo kọkọ ko awọn ejola Burma yi wa si ibudo omi Florida.

Awọn ejola wọnyi taaye ti gba a maa tobi ti wọn a si maa gun ni iwọn ẹsẹ bata mejidinlogun.

Ohun ti wọn n jẹ pọ nibi ti wọn wa yi to si jẹ nkan to n mu ki wọn maa tobi gidi gaan.

''Mike Kirkland to jẹ ọga onimọ nipa itọju ayika sọ pe awọn ejola yi n ṣe akoba nipa jijẹ awọn ẹranko kekeeke miran to wa ni ayika wọn.

Mike lagbatẹru eto ti wọn gbe kalẹ lati mu adinku ba iye awọn ejola to wa lyika Florida yii.

Aworan lati ibi idije ejola mimu to waye lọdun 2022 Python Challenge

Oríṣun àwòrán, Water Management District

Kirkland sọ pe adinku ida 90-95% ti ba iye awọn eranko bi ẹmọ ati okete to wa i ayika nitori bawọn ejola ṣe pọ ni agbegbe yii lati igba ti wọn bẹrẹ si ni ko aọn ejola yi wa sibẹ.

Iwadii kan fihan pe adinku ba iye awọn ẹranko kan bi ehoro ti wọn ko ri mọ layika naa.

''Ni nkan bi ogun ọdun ṣeyin, witiwiti lawọn ẹranko yi maa n ṣere layika yi mọ o ti di inira bayii lati ri agbọnrin,igala tabi ehoro nibi yii.Wọn ti jẹ gbogbo wọn tan''

Lati fidi ọrọ yi mulẹ, Kikland ṣafihan fọnran fidio kan nibi ti ejola kan ti fun ọoni kan lẹmi pa lọdun 2017.

Ọgbọn ti wọn da ree

Nigba ti wọn ṣe agbekalẹ eto yi wọn faaye gba awọn ọdẹ ejola yi lati maa wa wọn kaakiri gbogbo agbegbe ti wọn le wa.

Oṣu mẹta ni wọn lero lati kọkọ fi ṣeto yi amọ bayi o ti pe odindi ọdun mẹjo ti wọn ti wa lẹnu rẹ.

Wwọn ti gba ilọpo meji iye awọn oṣiṣẹ ti wọn fi bẹrẹ eto naa.

Lọwọlọwọ bayii awọn oṣiṣẹ aadọta lo n ṣiṣẹ labẹ eto ti Kirkland gbe kalẹ yi.

Wọn si tan kaakiri agbegbe mẹsan to kaari ipinlẹ ati ilẹ to jẹ ti ijọba apapọ.

Lati igba ti wọn ti ṣe agbekalẹ rẹ eto yi ti ribi mu awọn ejola 8,565 kaakiri i[pinlẹ naa.

Amy Siewe nibi to ti di ejola mu

Oríṣun àwòrán, Amy Siewe