Wo ìdí tó fi 'lòdì sófin bí iléeṣẹ́ ológun ṣe ní àwọn ń wá afurasí mẹ́jọ̀ lórí ikú àwọn sọ́jà ní Delta

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X
Agbẹjọro agba ati ajafẹtọọ ọmọniyan, Femi Falana(SAN) ti sọ pe o lodi sofin bi ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti kede pe awọn n wa afurasi mẹ́jọ to lọwọ ninu iku awọn ọmọ ogun mẹtadinlogun ti wọn ṣekupa nipinlẹ Delta.
Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2024 ni Aarẹ Bola Tinubu, awọn gomina, mọlẹbi ati awọn eekan mii peju sibi eto isinku awọn ọmọ ologun naa ni aaye isinku awọn ọmọ ologun Naijiria to wa niluu Abuja.
Ninu atẹjade kan ti Falana fi sita ni o ti ṣalaye pe bi ileeṣẹ ologun ṣe kede pe awọn n wa awọn afurasi naa lai gba aṣẹ lati ile ẹjọ, lodi si ofin.
Ọgbẹni Falana ni ki ijọba paṣẹ fun ileeṣẹ ologun lati yọwọ kuro ninu iwadii awọn afurasi ti wọn gbagbọ pe wọn lọwọ ninu iṣekupani awọn ọmọ ogun mẹtadinlogun naa.
Ajafẹtọọ naa ṣalaye pe ẹsun iṣekupani yii kii ṣe laarin ologun si ologun, nitori naa, ileeṣẹ ologun ko laṣẹ lati ṣe iwadii lori rẹ.
Falana ni "ti ijọba apapọ ba kọ lati yọwọ ileeṣẹ ologun kuro ninu iṣẹ iwadii iṣekupani awọn sọja ti wọn pa ni Delta, ẹjọ naa le ma kẹsẹ jari."
Ni ọjọ kẹrinla oṣu Kẹta l'awọn eeyan kan ṣekupa sọja mẹtadinlogun eyi ti ọga mẹta wa ninu wọn, nibi ti wọn ti n lọ pẹtu sija niluu Okuama ni ipinlẹ Delta.
"Ileeṣẹ ologun gbọdọ mọ pe ko laṣẹ lati fi ọwọ ofin mu eeyan, fi eeyan si ahamọ tabi pe araalu lẹjọ , niwọn igba ti ẹni naa ki i ba ti ṣe ologun.
Mo ranti ẹjọ ti ileeṣẹ ologun pe Ọmọwe Isa Perry Brimah, adajọ Ijeoma Ojukwu fidi rẹ mulẹ nigba naa pe ileeṣẹ ologun ko laṣẹ lati kede pe awọn n wa Ọmọwe Brimah gẹgẹ bi ọdaran lai tẹle alakalẹ ofin.
Bakan naa ni adajọ tun sọ pe ileeṣẹ ọm'ogun ko le fi ọwọ ofin mu Ọmọwe Brimah lai fa a le awọn ọlọpaa lọwọ," Falana ṣalaye.
Ti ẹ o ba gbagbe, owurọ Ọjọbọ to lọ ni ileeṣẹ ologun Naijiria kede afurasi eeyan mẹjọ ti wọn n wa lori iku awọn ṣọja mẹtadinlogun ọhun.
Lara wọn ni ọba to ti fi ara rẹ silẹ fawọn ọlọpaa bayii.
Awọn meje yooku ni : Ọjọgbọn Ekpekpo Arthur, Andaowei Dennis Bakriri, Akevwru Daniel Omotegbo ati Akata Malawa David.
Awọn mii tun ni Sinclear Oliki; Oghenerukeywe; Reuben Baru, ati Igoli Ebi.















