Àwọn agbébọn yabo ṣọ́ọ̀ṣì nípìnlẹ̀ Ogun, wọ́n jí èèyàn méjì gbé lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fidirẹ mulẹ pe, lootọ ni awọn agbebọn kan yabo ile ijọsin Celestial Church of Christ kan, to wa ni agbegbe Mowe, ijọba ibilẹ Obafemi/Owode, nipinlẹ naa.
Iroyin sọ pe Ọjọ́bọ ni wọn ji Oladapo Seyifunmi ati Oluboboye Abiola, gbe, ni abule Oriyanrin, Mowe.
Agbẹnusọ ọlọpaa, Odutola sọ pe, kete ti wọn ji awọn eeyan naa gbe, ni awọn afurasi ajinigbe ọhun gba inu igbo didi kan to wa lẹyin ile ijọsin naa salọ.
Bakan naa lo sọ pe awọn ọlọpaa ati àwọn oṣiṣẹ alaabo míì ti bẹrẹ si ni wa wọn ni kiakia.
Sugbọn nigba ti yoo fi di owurọ ọjọ Abamẹta, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ẹni kan ninu eeyan meji ti wọn ji gbe, ti gba ominira.
Eyi jẹyọ ninu atẹjade ti wọn fi sita loju opo ayelujara X.
"Inu wa dun lati fi to araalu leti pe, Oladapo Seyifunmi, Oluṣọ Aguntan ijọ Celestial ti wọn ji gbe, ti gba ominira."
Ọlọpaa sọ pe eyi ri bẹẹ, nipasẹ bi awọn ọlọpaa, Amotekun, ati ọdẹ ibilẹ ati ẹgbẹ́ awọn fijilante, ṣe tu inu igbo naa yẹbẹyẹbẹ.
Bakan naa ni wọn ni Ọgbẹni Oladapo ti darapọ mọ ẹbi rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post












