Ọkùnrin kan dèrò ilé ẹjọ́ fún ẹ̀sùn jíjí fùfú, ìkòkò ọbẹ̀ àti àwọn nǹkan mìí

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti ti wọ ọkunrin kan, Ojo Monday, ẹni ogun ọdun lọ siwaju Ileẹjọ fun ẹsun pe o ja wọ ile oni ile, to si tun jale.
Ọlọpaa to lewaju fun ẹjọ naa, Moyosola Adesola sọ fun ileẹjọ pe afurasi naa ṣe ijamba yii lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta ni nnkan bi aago mejila ni agbegbe Falegan, niluu Ado Ekiti.
Afurasi naa tako ẹjọ naa, to si ni ohun ko mọ ohunkohun nipa ẹsun naa.
Ẹsun ti Ọlọpaa fi kan Ojo ni pe o ja wọ ile kan to jẹ ile Ajala Modupe, to si ji Indomie , elo ọbẹ, iyọ, alubọsa, fufu ati isasun ọbẹ ti gbogbo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọọdurun naira.
Ajala ni ẹsun naa lodi si ofin to de iwa ọdaran ni ipinlẹ Ekiti ti ọdun 2021.
Agbẹjọro fun afurasi, Olayinka Opaleke rọ ileẹjọ lati fi aye fun afurasi naa lati gba beeli.
Adajọ Ileẹjọ naa, Taiwo Ajibade buwọlu beeli naa fun apapọ ẹgbẹrun lọna aadọta naira, to si tun sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹrin.
Ọkùnrin kan di èèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tó jí Kùránì àti fóònù

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ilé ẹjọ́ Grade 1 Area Court tó wà ní agbègbè Lugbe, Abuja ti sọ arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Terkaa Akishi sí ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ẹ̀dógún fẹ́sùn wí pé ó jí fóònù àti Kurani ní Mọ́ṣáláṣí.
Ní agbègbè Asokoro ni Abuja ni Mọ́ṣáláṣí tí ọkùnrin náà ti jí Kurani àti fóònù náà wà.
Adájọ́, Malam Aliyu Kagarko ló ní kí Akishi ló máa fi aṣọ péńpé roko ọba fẹ́sùn ìwà olè jíjà náà.
Àmọ́ Adájọ́ Kagarko ní tí Akishi kò bá fẹ́ sun ẹ̀wọ̀n, yóò san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.
Olùpẹjọ́ fún ìjọba, Ọ̀gbẹ́ni Emeka Ezeganya sọ fún ilé ẹjọ́ pé Isah Balikisu ti ilé iṣẹ́ ọmọ ogun Asokoro ló lọ fi ẹjọ́ olè náà sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá Asokoro lọ́jọ́ Kẹrìnlá oṣù Kẹta.
Ó ní Akishi wọ inú Mọ́ṣáláṣí náà tó sì jí fóònù àti Kurani méjì àmọ́ àwọn kò lè sọ pé iye ni àwọn nǹkan tó jí náà jẹ́.
Ó ṣàlàyé pé àwọn ọlọ́pàá ti rí fóònù àtàwọn Kurani náà gbà padà lọ́wọ́ Akishi lásìkò tí wọ́n ń ṣe ìwádìí.
Ezeganya fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìwà olè tí Akishi hù lòdì sí òfin orílẹ̀ èdè yìí.















