Wo bí o ṣe lè ṣ'àtúnṣe orúkọ, ọjọ́ ìbí àtàwọn nǹkan míì lórí NIN láì lọ sí iléèṣẹ̀ NIMC

Aworan foonu ati kaadi NIN

Oríṣun àwòrán, NIMC/X

Ajọ NIMC to n ri si nọmba idanimọ NIN ti ṣe agbekalẹ ọna to rọrun fun araalu lati maa ṣe atunṣe tabi ayipada orukọ wọn, ọjọ ibi, nọmba foonu at'awọn nnkan mii lori nọmba idanimọ NIN wọn ti ko si ni nilo lati lọ si ọfiisi ajọ naa mọ.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n koju ipenija lati ṣe awọn atunṣe yii pẹlu bi ijọba ṣe kan an nipa fawọn eeyan lati so kaadi SIM foonu ati apo aka-n-ti banki wọn pọ mọ nọmba NIN wọn.

Ọpọ ninu awọn eeyan yii lo ti n lọ si ọfiisi ajọ NIMC lati se eleyii, amọ, ko rọrun nitori ọpọ eeyan.

Laipẹ yii ni ijọba apapọ sọ fun awọn ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ wi pe, ki wọn ja gbogbo awọn ti ko ba ti so nọmba foonu wọn pọ mọ nọmba NIN wọn kuro lori ila ipe.

Amọ, ajọ NIMC ti sọ eyi di irọrun bayii nipa aapu ti wọn ṣe, eleyi ti ẹnikẹni le lo fun atunṣe ti wọn ba fẹ ṣe lori nọmba NIN wọn.

Wọnyi ni awọn igbesẹ ti o ni lati gbe fun atunṣe lori nọmba NIN rẹ:

  • Bẹrẹ pẹlu ayẹwo nọmba NIN rẹ ki o si wọ ori aapu ajọ NIMC lọ
  • Lọ si ibi ti aye wa fun ọjọ ibi ki o si tẹ ọjọ ibi rẹ, oṣu ati ọdun sibẹ.
  • Igbesẹ kẹta ni pe owo sisan fun atunṣe ti o fẹ ṣe lori nọmba idanimọ NIN rẹ.
  • Lẹyin ti o ba ti sanwo tan, fi nọmba satifikeeti NPC (ajọ to n mojuto ọjọ ibi) rẹ sori aapu naa, kete ni aapu yii yoo gbe ọjọ ibi rẹ jade.
  • Ranti lati fi nọmba satifikeeti NPC rẹ sii pẹlu awọn iwe mii to lọ pẹlu rẹ.
  • Fi atunṣe ti o ṣe ranṣẹ lori aapu yii.
  • Ma gbagbe lati ṣe ayẹwo aye to wa fun ijẹrisi awọn iwe ẹri ti o lo ki o to fi atunṣe rẹ ranṣẹ.
  • Gba iwe pelebe risiiti atunṣe ti o ṣe lori aapu NIMC.
  • Lẹyin ibuwọlu ajọ NIMC, waa ri idaniloju atunṣe ti o ṣe gba ninu apo igbọrọkaye rẹ(email). Bakan naa ni o ni anfaani lati tẹ ẹ jade lori aapu naa.
Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Èlò lo nílò láti fi ṣe àwọn àtúnṣe yìí?

Gẹgẹ bi a ti ṣe sọ ṣaaju, kii ṣe ọjọ ibi nikan ni eeyan le ṣe ayipada tabi atunṣe si lori aapu yii, ole ṣe atunṣe si nọmba ibanisọrọ to wa lori rẹ, adirẹsi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Amọ awọn atunṣe ko ba ọfẹ nitori ẹni to ba ṣe awọn atunṣe naa yoo nilo lati san owo fun NIMC lori aapu ọhun.

₦16,340 ni ẹni to ba fẹ ṣe ayipada si ọjọ ibi rẹ yoo san gẹgẹ bi atẹjade NIMC nigba ti awọn to ba fẹ ṣe ayipada si orukọ, adirẹsi ati imeeli wọn maa san ₦1,522.50.

Kí ni àwọn nǹkan tí o nílò láti ṣàtúnṣe sí nọ́mbà ìdánimọ̀ rẹ?

Fun atunṣe si orukọ, o nilo:

  • Iwe ontẹ ile ẹjọ
  • Atẹjade orukọ tuntun lori iwe iroyin
  • Iwe ẹri igbeyawo (fun ẹni to ba fẹ tori igbeyawo parọ orukọ)

Fun atunṣe si adirẹsi o nilo:

  • Iwe tẹ fi n san owo ina mọnamọna
  • Iwe ile ti o n gbe
  • Atẹjade idunaadura ile ifowopamọ rẹ
  • Ibuwọlu olori agbegbe ibi ti o n gbe

Fun atunṣe si nọmba ibanisọrọ rẹ, o nilo

  • Ẹri lati ileeṣẹ ọlọpaa

Fun atunṣe si ipele ẹkọ, o nilo

  • Iwe ẹri ile ẹkọ to fẹ fi kun-un

Fun atunṣe si iṣẹ, o nilo

  • Lẹta ti wọn fi gba ẹ siṣẹ