Wo àwọn orílẹ̀èdè tí ìlédìí àgbàlagbà ti pọ̀ ju ti ọmọdé lọ

Agbalagba ati ọmọde
    • Author, Mariko Oi
    • Role, Economic journalist

Ileeṣẹ kan to n se iledi lorilẹede Japan ti kede pe, oun yoo dẹkun ati maa ṣe iledi ọmọde lọna ati doju kọ iledi awọn agbalagba nikan.

Oji Holdins jẹ ọkan lara awọn ileeṣẹ to fi irufẹ ikede yii sita latari bi awọn eeyan ṣe n darugbo ni Japan, ti awọn araalu si n kọ lati maa bimọ.

Lọwọ yii, iledi awọn agbalagba ta ju iledi awọn ọmọde lọ lorilẹede ọhun.

Apapọ iye ọmọ ti wọn bi ni Japan lọdun 2023 jẹ 758,631, eyii to fi ida 5.1% din ju ti ọdun 2022 lọ.

Iye awọn ọmọ naa lo kere julọ ni Japan lati nnkan bii ọgọrun ọdun o le ogun ọdun sẹyin.

Ni bayii, iye iledi ọmọde ti wọn n ṣe ni Japan laarin ọdun kan jẹ nnkan bii irinwo miliọnu, nigba ti iledi agbalagba pọ ju bẹẹ lọ.

Lọdun 2011, ileeṣe to tobi julọ to n ṣe iledi sọ pe iledi awọn agbalagba ti pọ ju ti awọn ọmọde lọ.

Kii ṣe Japan nikan ni irufẹ nnkan bayi ti n ṣelẹ

Diapers

Oríṣun àwòrán, getty images

Awọn onimọ ti sọ pe kii ṣe Japan nikan ni iye ọmọ ti wọn n bi ti n dinku lagbaye.

Gẹgẹ bi ohun ti wọn sọ, lara awọn idi ti arugbo fi n pọ ju ọmọ wẹwẹ lọ ni bi igbeyawo ṣe n tuka laipẹ ọjọ, bi ọpọ awọn obinrin ṣe n ṣiṣẹ ati bi owo ti eeyan fi n tọ ọmọ ṣe n pọ sii.

Lara awọn orilẹ mii to n koju irufẹ nnkan bayii yatọ si Japan ni Hong Kong, Singapore, Taiwan ati South Korea.

Koda, South Korea ni orilẹede ti iye awọn ọmọ tuntun ti dinku julọ lagbaye.

Ni China, iye ọmọ ti wọn n bi naa ti dinku ju ti tẹlẹ, amọ gẹgẹ bii Japan, wọn ti n wa ọna lati ṣe iwuri fun awọn araalu lati maa bimọ si.

Diapers

Oríṣun àwòrán, getty images