Ológun pàwọn agbébọn tó fẹ́ palẹ̀ àwọn olùjọ́sìn mọ́

Aworan awọn ọmọ ogun Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ajinigbe kan, to fẹ yabo ile ijọsin kan ni Taraba, ti kagbako iku ojiji lọwọ awọn ọmọ ogun lorileede Naijiria.

Yatọ si pe wọn gbe iwe ibawi le wọn lọwọ, awọn ọmọ ogun tun gba ibọn ati ọta ibọn lọwọ awọn alaburu marun un yi.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi soju opo wọn ni Instagram, ileeṣẹ ologun sọ pe eeyan kan lo tawọn lolobo pe awọn agbebọ̀n kan n gbero lati ṣe ikọlu si ile ijọsin ni Wukari.

Iroyin ti wọn gbọ ṣaaju ọhun, lo ṣokunfa bi awọn ọmọ ogun ṣe lọ koju awọn ajinigbe yii.

Lowurọ kutu ọjọ keji oṣu kẹrin, ni awọn ọmọ ogun 93 Battalion to wa ni Wukari ni ipinlẹ Taraba, rẹro de awọn janduku agbebọn ọhun, ti wọn si gbena woju wọn.

Nibi tawọn mejeeji ti koju ara wọn, ti iro ibọn si n dun kikankikan, ni wọn ti mu mẹrin balẹ ninu awọn obilẹjẹ ẹ̀dá wọnyi.

Ileeṣẹ ologun ṣalaye pe awọn ri ibọn AK 47 meji ibọn ṣakabula kan ati ọta ibọn AK 47 meji gba.

Ẹwẹ, awọn ọmọ ogun tun ṣe ikọlu si awọn agbebọn mii ṣaaju ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹta lagbegbe Chanchanji ni ijọba ibilẹ Takum.

Ajinigbe kan fi iku ṣe ifa jẹ lọjọ taa n wi yi ti awọn ologun si ri foonu, ibọn ibilẹ ati ọta ibọn gba lọwọ ajinigbe naa.

Lẹnu lọọlọ yi awọn ologun ni Naijiria ti n koju awọn ajinigbe ati ọdaran agbebọn mii to n da omi alaafia Naijiria ru.

Lai pẹ yi ọrọ ijinigbe ti wa gbogo ti awọn to n hu iwa yi ko fi mọ ni ti agbalagba nikan mọ.

Ni ipinlẹ Kaduna wọn ji awọn akẹkọọ 287 kan gbe ki wọn to pada gba itusilẹ.

Awọn ajinigbe yi beere owo idoola biliọnu Naira kan lọwọ awọn araalu ti wọn si ni ti wọn ko ba san owo naa, awọn yoo bẹre si ni pa awọn to wa ni ahamọ wọn.