"Àwọn òkú ní Mọ́ṣúárì UCH ti ń rùn, a kò le ra Dísù sí gẹnẹratọ torí èlé owó epo"
Apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ilera nile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun Oyinbo, UCH, niluu Ibadan ti kede pe aago mẹjọ owuro si mẹrin irọlẹ ni awọn yoo fi maa ṣiṣẹ nitori aisi ina ọba ninu ọgba ile iwosan nla naa.
Ipinnu yi ni wọn ṣalaye pe yoo gberasọ bẹrẹ lati Ọjọru, tii ṣe ọjọ Kẹta oṣu Kẹrin.
Ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni ileeṣẹ to n ṣe akoso ina ọba ni agbegbe naa, IBEDC, ja ina UCH nitori obitibiti gbese to le ni irinwo milliọnu Naira ti ile iwosan naa jẹ.
Adari ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni UCH, Arakunrin Oludayo Olabampe ṣe alaye fun BBC Yoruba wi pe ọpọlọpọ inira ni aisi ina ijọba ti mu ba iṣẹ awọn oṣiṣẹ, awọn alaisan ati ti awọn to n tọju wọn.
Nitori idi eyii ni ẹgbẹ naa fi kede pe ko ni rọrun lati maa ṣiṣẹ l'oru mọju gẹgẹ bi wọn ti n ṣe tẹlẹri.

Òṣìṣẹ́ UCH mú àdínkù bá iye wákàtí ìṣẹ́ torí ṣégeṣège iná mọ́nàmọ́nà
Olabampe ni aago mẹjọ owurọ si mẹrin irọlẹ ni awọn yoo fi maa ṣiṣẹ titi ti wọn yoo fi wa ojutu si iṣoro ina ọba ninu ọgba ile iwosan naa.
O ni awọn ti ṣe ipade pọ pẹlu ajọ to n pin ina ni agbegbe naa, IBEDC ati awọn alakoso UCH lati mọ ibi ti ọrọ de duro ki wọn to fun awọn alakoso naa ni gbedeke ọjọ meje lati wa ojutu si ọrọ ina ọgba.
Gbendeke yi to bẹrẹ lati ọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹta titi di ọjọ Keji oṣu Kẹrin wa sopin ki wọn to gbe igbeṣe lati mu iyipada ba wakati iṣẹ wọn.
Olabampe ke si ijọba ati awọn ẹlẹyinju aanu l'awujọ lati dide iranlọwọ fun UCH.
O ni eleyi di dandan nitori ina ti ko si n da ẹmi awọn alaisan kan legbodo.
Bẹẹ lo si ni ibi igboku si, mọṣuari, ile iwosan naa ti fẹ maa run nitori aisi yinyin ti wọn fi n toju ara oku.

Àlàyé rèé lórí ìdí tí UCH ṣe jẹ gbèsè owó iná to to N435m Naira - Ọ̀gá àgbà
BBC kan si Giwa agba UCH, Ọjọgbọn Jesse Otegbayo lori ọrọ yii, alaye ti o ṣe fun akọroyin wa ni pe ki oun to gba iṣakoso ile iwosan naa ni gbese ti wa nilẹ.
O ni oṣooṣu si ni awọn n rọ gbese naa san ki o to di wi pe omi pọ ju ọka lọ.
Otegbayo ni ninu ọdun yii nikan, awọn ti san gbese aadọjọ milliọnu Naira, ṣugbọn ko ka nnkankan ninu gbese to le ni irinwo miliọnu Naira, ₦435m ti awọn n jẹ.
O tẹsiwaju wi pe awọn ti kọ iwe si ijọba ati awọn ẹlẹyinju aanu l'awujọ lati dide iranlọwọ fun ile iwosan naa ki awọn ipenija yi to fẹju ju bayii lọ.
"Ofin ijọba ko faaye gba osisẹ lati se adinku wakati iṣẹ"
Lori ikede ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ṣe nipa adinku akoko ti wọn fi n ṣiṣẹ, Otegbayo ni ko si ofin ijọba apapọ kankan to fi aye gba irue, pe ki oṣiṣẹ maa ṣe iṣẹ aabọ ki o si fẹ maa gba owo oṣu.
Alaye ti o ṣe ni pe bi wọn ba fi agidi gun le ilana tuntun naa, "o ni bi wọn ṣe n da abẹ fun ọmọ tuntun nilẹ Yoruba".
Ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹta ọdun yii ni ileeṣẹ to n pin ina, IBEDC ja ina ile iwosan UCH niluu Ibadan nitori gbese ti wọn jẹ.
Ọrọ ti IBEDC mu bọ ẹnu ni pe ile iwosan naa gbudọ kọkọ san igbalelaadọta millionu Naira, ₦250Million lara gbese ti wọn jẹ, pẹlu adehun pe iyoku yoo jẹ sisan pada loṣooṣu, ki awọn to so ina wọn pada.
















