North Korea missile tests: Orílẹ̀-èdè North Korea ṣe ìfilọ́lẹ̀ àdó olóró tó tóbi jùlọ láti ọdún 2017

Oríṣun àwòrán, EPA
Orilẹ-ede to wa lẹgbẹ wọn, South Korea, sọ pe ni nakn bi aago mẹjọ ku iṣẹju mẹjọ ni owurọ ọjọ Aiku ni wọn ṣe ifilọlẹ naa.
Japan, South Korea ati United Sates si ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ọhun, to jẹ igba keje ti North Korea ṣe iru nkan bẹẹ loṣu yii nikan.
Ṣaaju ni ajọ United Nations fi ofin de North Korea pe ko gbọdọ dan ado oloro kankan wo mọ, ti wọn si ka ijiya to rọ mọ.
Ṣugbọn ni gbogbo igba ni orilẹ-ede naa to wa ni Ila oorun Asia ma n tapa si ikilọ naa.
Olori orilẹ-ede ọhun, Kim Jong-un ti jẹjẹ pe gbogbo nkan ni oun yoo fi mu ki eto aabo wa fun orilẹ-ede oun.
Awọn alaṣẹ ni Japan ati South Korea sọ pe ado oloro naa rìn to ẹgbẹrun meji kilomita, to si lo to ọgbọn iṣẹju lati de ẹgbẹrin kilomita.
Inu okun ni orilẹ-ede Japan lo balẹ si.
Orilẹ-ede America sọ pe didan awọn ado olor naa wo tako agbekalẹ ajọ agbaye, to si kesi North Korea pe ko jawọ ninu mimu inu bi oun.
Kinni aarẹ orilẹ-ede South Korea sọ?
Aarẹ South Korea, Moon Jae-in sọ pe ado oloro ti wọn ṣẹṣẹ filọlẹ yii ran oun leti iporuru ọkan to ti n waye lati ọdun 2017, ti North Korea ti bẹrẹ si ni ṣe ifilọlẹ awọn ado oloro nlanla.
Ninu ọrọ kan to sọ ni ọdun naa, Ọgbẹni Kim kesi awọn ọmọ ogun orilẹ-ede rẹ pe ki wọn o wọ ara wọn ni agbara pẹlu imọ ẹrọ to lagbara.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lati igba naa si ni wọn ti n sẹ ifilọlẹ ọpọlọpọ nkan ija oloro.
Ni ibẹrẹ oṣu yii, orilẹ-ede America tun ka awn ijiya kan silẹ fun North Korea fun awọn ado oloro to ti ṣe ifilọlẹ wọn sẹyin.
Ijiroro laarin orilẹ-ede mejeeji ko lọ deede lati igba ti oe Biden ti di aarẹ ilẹ America.












