Liberia Prisons: Ìṣòrò àìsí oúnjẹ, ibùgbé àti aṣọ n bá àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Liberia fínra

Oríṣun àwòrán, GLENNA GORDON/AMNESTY INTERNATIONAL
Ni ibẹrẹ oṣu yii ni ounjẹ awọn ẹlẹwọn tan, ni ọgba ẹwọn gboogi to wa ni Liberia. Iṣẹlẹ yii si lo tu aṣiri awọn iṣoro miran ti ti n ba ileeṣẹ ọgba ẹwọn finra ni orilẹ-ede naa fun ọjọ pipẹ
Aisi ounjẹ kan gbogbo ọgba ẹwọn mẹẹdogun to wa ni orilẹ-ede naa, eyi to mu ki meji ninu wọn dawọ gbigba ẹlẹwọn tuntun duro.
Lẹyin ọjọ meji ti ebi ti fẹ pa awọn ẹlẹwọn ku, ni ẹlẹyinju aanu kan ni awujọ gbe ounjẹ wa fun wọn - ṣugbọn iṣoro airowo na ati bi eero ṣe pọju ni awọn ọgba ẹwọn naa ko ti i ni ojutu.
Fun apẹẹrẹ, ni ọgba ẹwọn Monrovia Central Prison, egbeje ẹlẹwọn lo wa ninu aaye ti ko le gba to irinwo ẹlẹwọn.
Lootọ ni ita ọgba ẹwọn naa rẹwa, ṣugbọn iṣoro to n ba wọn finra ninu ile kii ṣe kekere.
- Àwọn nǹkan mẹ́ta tí a kò tíì mọ̀ nípa Covid-19 lẹ́yìn tí àrùn náà bẹ́ sílẹ̀ rèé
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bí wọ́n ṣe rí Abba Kyari, Obi Cubana níbi ìgbéyàwò ọmọ ọ̀gá ọlọ́pàá Alkali Baba
- Nkan dẹnu kọlẹ̀ ní àwọn agbègbè kan ní America nítorí ìjì líle
- Ọlọ́pàá Ogun mú ọ̀dọ́ mẹ́ta tí kò tó ọdún 20 níbi tí wọ́n ti n fi ọ̀rẹ́bìnrin ọ̀rẹ́ wọn ṣe òògùn owó
- Abdulsalami ní kò sẹ́ni tó pa MKO Abiola, àìsàn ló pa á, ẹbí Abiola yarí
Awọn ẹlẹwọn to ba awọn akọroyin sọrọ nibi ayẹyẹ kan to waye nibẹ sọ pe abọ irẹsi kan pere ni ijọba n fun awọn ni ojoojumọ. Lẹyin rẹ, ko si ounjẹ miran di ọjọ keji.
Alamojuto ọgba ẹwọn Monrovia Central Prison, Varney G Lake, sọ pe oun gba pe titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ ni bi awọn ẹlẹwọn ṣe n pọju.
Bakan naa lo fi ẹdun ọkan rẹ han si bi awọn ile ati oun elo to wa ninu ọgba ẹwọn naa ṣe ti dẹnukọlẹ.

Oríṣun àwòrán, GLENNA GORDON/AMNESTY INTERNATIONAL
Kii sẹ ọgba ẹwọn Monrovia Central nikan ni ọrọ yii kan
Oludari apapọ fun ọgba ẹwọn ni Liberia, Rev S Sainleseh Kwaidah fidirẹ mulẹ pe lootọ ni airi ounjẹ gidi fun awọn ẹlẹwọn wa lara awọn ipenija gboogi ti oun n koju.
O ni eyi ko ṣẹyin bi ijọba kii ṣe tete yọnda owo to yẹ fun ọgba ẹwọn loṣooṣu.
O sọ fun BBC pe fun apẹẹrẹ, owo ounjẹ fun oṣu Kẹsan-an ko tẹ awọn lọwọ titi di ẹyin ọdun Keresimesi.
O ni niṣe ni awọn alamojuto ọgba ẹwọn n ya owo kiri lati fi bọ awọn ẹlẹwọn to wa ni ọdọ wọn.
"Gbogbo awọn ọgba ẹwọn wa ni ko ba ìgbà mu mọ, ti wọn si nilo atunṣe."

Oríṣun àwòrán, GLENNA GORDON/AMNESTY INTERNATIONAL
Lara nkan to tun sọ ni pe ko si irinṣẹ fun eto ilera, to fi mọ aṣọ fun awọn ẹlẹwọn ati awọn wọ́dà.
O ti le ni ọdun mẹwaa ti awọn ẹlẹwọn ti ri aṣọ gba kẹhin, ajọ UN si lo fun wọn.
"Ko tun si ọkọ̀ lati fi gbe ẹlẹwọn lọ sile ẹjọ. Kẹ̀kẹ́ ẹlẹsẹ mẹta la fi ma n gbe ẹlẹwọn. Eyi ko bojumu rara, nitori pe awọn kẹkẹ naa ko ni ilẹkun.
Awọn ọkọ ti ajọ UN fi silẹ ni opin iṣẹ ilaja to sẹ lọdun mẹfa sẹyin, ti dẹnu kọlẹ."
Minisita fun eto idajọ, Frank Musa Dean, sọ fun bBC pe ijọba mọ awọn iṣoro to n koju ọgba ẹwọn, nitori pe wọn wa ninu akọsilẹ.
"Ṣugbọn igbagbọ wa ni pe awọn aṣofin yoo buwọlu owo to to yanju awọn iṣoro naa."












