Kó s'éwu fún Nàìjíríà lórí b'áwọn ológun ṣe ń dìtẹ̀ gbàjọba l'Áfíríkà- Ìjọba àpapọ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ijọba apapọ ti ke pe awọn ọmọ Naijiria lati fi ọkan balẹ lori bi awọn ologun ṣe n gbajọba kaakiri ilẹ Afirika.

Nigba to ba awọn akọroyin sọrọ, minisita eto iroyin ati ilanilọyẹ, Mohammed Idris ṣalaye pe orilẹede Naijiria ti kọja orilẹede tàwọn ologun ti le gba ijọba mọ.

Ọgbẹni Idris sọ pe awọn ọmọ Naijiria ti tẹwọ gba ijọba awaarawa eleyii to jẹ ki ijọba oloṣelu fidi mulẹ.

Minisita naa sọ pe bi awọn ologun ti ṣe n gbajọba l'awọn orilẹede iwọ oorun Afrika papaa julọ ni orilẹede Niger to wa lẹgbẹẹ Naijiria ko tumọ sí pe ki awọn ọmọ Naijiria maa bẹru pe iru ikan bayii le ṣẹlẹ.

"Mo le fi igboya sọrọ pe awọn ologun ko le gbajọba ni Naijiria.

O ti ṣe diẹ naa ti a tí n ṣe ijọba awaarawa ni Naijiria, a kii ṣe alejo mọ ninu ijọba oloṣelu.

"Nitori naa, ko si ewu lori ọrọ awọn ologun rara," minisita ṣalaye.

Ẹwẹ, awọn ọgagun fẹhinti kan ti kilọ pe iku to n pa ojugba ẹni, owe lo n pa fun ni.

Wọn ni oju ni alakan fi n sọ ori, eyi to tumọ sí pe ọna kan gboogi ti ijọba fi lè gbegi dina iditẹgbajoba l'Afirika ni kí awọn oloṣelu tàwọn araalu dibo yan maa ṣe ijọba tí yoo maye dẹrun fawọn araalu.

Bakan naa ni wọn sọ pe awọn oloṣelu to wà nípò ni lati maa tẹle iwe ofin orilẹede ninu iṣejọba wọn.

Awọn ajagun fẹhinti náà tun kilọ pe awọn oloṣelu to n ṣe ijọba gbọdọ yago fun iwa ta ni yoo mu mi, ti wọn ko ba fẹ fawọn ologun laye lati doju ijọba bolẹ.

Ni Ọjọru ọsẹ yii ni awọn ologun tun dìtẹ gbajọba ni orilẹede Gabon nibi ti wọn ti doju ijọba Aarẹ Ali Bongo bolẹ.