NLC kéde Ìyanṣẹ́lódì ọjọ́ méjì lórí owó ìrànwọ́ epo

Aworan iwode NLC

Ẹgbẹ oṣisẹ lorilẹede Naijiria, Nigeria Labour Congress ti kede pe awọn yoo gunle iyanṣẹlọdi onikilọ ọlọjọmeji ti yoo bẹrẹ lati ọjọ karun un si ọjọ kẹfa oṣu kẹsan na.

Aarẹ ẹgbẹ naa, Joe Ajaero lo gbe ikilọ yii lati ṣe ifẹhonuhan lori ijọba orilẹede Naijiria ṣe n fi aye ni awọn araalu lara, paapa bi wọn ṣe yọ owo iranwọ bẹntirolu.

Ajaero sọ ẹlẹyi niluu Abuja pe awọn gbe igbesẹ yii ipade ijọba apapọ niluu Abuja.

Yatọ si idunkoko iyansẹlodi, NLC fẹsun kan ijọba apapọ pe wọn fẹ mọ bi nnkan ṣe n lọ ninu ẹgbẹ naa paapa lori ọrọ ẹgbẹ awọn awakọ lorilẹede Naijiria, NURTW

Saaju ninu oṣu kẹjọ, Ẹgbẹ osisẹ NLC se ifẹhonuhan to si waye kaakiri orilẹede Naijiria.

"Idi ti a n fi se iyabsẹlodi lọjọ karun un ati ọjọ kẹfa oṣu kẹsan an ni lati jẹ ki ijọba mọ pe a n gberadi fun iyansẹlodi lọjọ gbọọrọ ni pari oṣu

"Ati lati ṣo fun ijọba apapọ kueo ni ọfisi ẹgbẹ awakọ niluu Abuja ti wọn gbe ẹsẹ le ni ilana ti ko ba ofin mu

"A ti ipinnu pe a yoo ṣe iwode nipinlẹ Imo ninu oṣu kẹsan an lati gbaradi fun iyansẹlodi ọlọjọ gbọọrọ nipinlẹ lati jẹ ki ijọba dekun fifi iya jẹ awọn osisẹ nipinlẹ naa.

"Bakan naa, a ti n gbaradi fun dida isẹ duro ni gbogbo ileeṣẹ ofurufu lorilẹede Naijiria ti wọn lọwọ ninu fi jẹ awọn osisẹ wọn."

Ki lo sẹlẹ saaju?

Lọjọ keji oṣu kẹjọ ọdun 2023 ni awọn osisẹ kaakiri orilẹede Naijiria bẹrẹ iwọde ati ifẹhonuhan kaakiri ipinlẹ mẹrẹrindinlogoji ati olu ilu Naijiria Abuja.

Lara ohun ti wọn n bere fun ni pe ki ijọba fopin si gbogbo rogbodiyan ti awọn ọmọ Naijiria n la kọja lẹyin ti ijọba yọ owo iranwọ bentiro.

Ẹgbẹ osisẹ gbe iwode naa de ile asofin orilẹede Naijiria ti Akojanu ile igbimọ asofin agba lorilẹede , Sẹnetọ Ali Ndume si ni ki awọn olori ẹgbẹ osisẹ NLC ati TUC lati fun wọn lọsẹ kan lati yanju gbogbo ibeere ẹgbẹ osisẹ fun ijọba apapọ

Ndume ni abadofin ti wa ni ile asofin to n pe fun atunse ileesẹ tomn pese epo bentiro, eyi ti yoo fopin si bi ijọba se n gbe epo lọ oke okun.

O rọ awọn olufẹhonuhan lati fun ile igbimọ asofinn ni ọsẹ kan lati yanju gbogbo ibeere wọn.