Fídíò Ààrẹ Ali Bongo tó ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ lẹ́yìn tí àwọn ológun gbàjọba lọ́wọ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Ali Bongo
Aarẹ orilẹ-ede Gabon, Ali Bongo ti bẹbẹ fun iranlọwọ lẹyin ti awọn ọmọ ogun gba ijọba lọwọ rẹ, ti wọn si fi si ahamọ ninu ile rẹ.
Lasiko to n sọrọ ninu fidio kan lo ti ke si awọn alatilẹyin rẹ lati lo ohùn wọn fun itusilẹ oun.
Ṣaaju asiko yii ni awọn ologun ti kọkọ kede lori ẹrọ amohunmaworan pe awọn ti gba ijọba lọwọ rẹ.

Wọn ni awọn ti wọgile esi idibo to waye lopin ọsẹ, eyii to gbe Ali Bongo wọle gẹgẹ bii Aare amọ ti ẹgbẹ alatako sọ pe o ni magomago ninu.
Awọn ologun na tun sọ pe awọn ti fi ṣikun ofin mu ọmọ ọkunrin Bongo fun ẹsun iditẹ.
Lẹyin naa ni wọn kede pe olori ẹṣọ alaabo ile Aarẹ, Brice Oligui Nguema ni yoo wa nipo Aarẹ Bongo.
Wọn ni lati Ọjọbọ ni awọn olugbe orilẹ-ede naa yoo gba ominiraa lati maa lọ sibi owo wọn bẹrẹ lati aago mẹfa aarọ si mẹfa irọlẹ.
Lati ọdun marundinlọgọta sẹyin ni mọlẹbi Bongo ti n tukọ orilẹ-ede naa bọ ki ologun to fopin si iṣejọba wọn lọdun yii.
Orilẹ-ede Gabọn jẹ okan gboogi lara awọn orilẹ-ede to ni epo rọbi ju nilẹ adulawọ.
Awọn koko nipa orilẹede Gabon ṣaaju iditẹgbajọba
Nibo ni Gabon wa? Iwọ oorun ilẹ Afrika ni Garbon wa, o ni ọpọ epo rọbi, amọ gbogbo eeyan orilẹ-ede naa ko ju 2.4 miliọnu lọ.
Ta ni Ali Bongo? Oun ni Aarẹ orile-ede Garbon lati ọdun 2009, amọ saaju iṣejọba rẹ, baba rẹ ni Aarẹ orilẹ-ede naa fun ọdun mọkanlelogoji.
Ni bayii, awọn ologun ti ni awọn ti fopin si iṣẹjọba ẹbi Bongo.
Ki lo fa iditẹgbajọba? Awọn ologun kọ lati tẹwọ gba esi idibo Aarẹ to waye lorilẹ-ede naa, eyii to gbe Bongo wọle, wọn si ni awọn gba ijọba naa lọwọ rẹ ki alaafia le jọba.












