Gabon, akọ̀tun nínú ọ̀pọ̀ ìdìtẹ̀gbàjọba ní Áfíríkà

Aarẹ Bongo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbọnmọgbọnmọ igbajọba awọn ologun pọ lawọn agbegbe kan ni Afrika lẹyin ti wọn gba ominira. Amọṣa lẹyin igba diẹ iṣejọba tiwantiwa fi ẹsẹ rinlẹ, o dabi ẹni pe awọn onikaki tun ti n le furukọkọ.

Iditẹgbajọba ni Gabon ni akọtun ninu ọwọja iditẹgbajọba awọn ologun bayii, paapaa kẹyin nnkan bi oṣu kan tawọn ologun ṣe bakan naa lorilẹede Niger.

Igba meji ọtọọtọ ni iditẹgbajọba waye ni Burkina Faso lọdun 2022, ti iditẹgbajọba miran si tun foriṣanpọn ni Guinea Bissau, Gambia ati erekuṣu Sao Tome and Principe.

Lọdun 2021, iditẹgbajọba mẹfa lo waye ni Afrika, mẹrin ninu wọn lo kẹsẹjari.

Nigba wo ni a le sọ pe iditẹgbajọba kẹsẹjari?

Iditẹgbajọba ni ọna aibofinmu ti awọn ologun tabi alagbada ba lo lati yẹ aga mọ awọn adari wọn nidi.

Iwadii awọn onimọijinlẹ meji kan lorilẹede Amẹrika, Jonathan Powell ati Clayton Thyne ni o le igba iditẹgbajọba to ti waye ni Afirika lati ọdun 1950 si asiko yii.

Awon Ologun kan n ya fọto pẹlu araalu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nnkan bi ilaji rẹ lo kẹsẹjari. Ọpọ igba si lawọn to wa nidi iditẹgbajọba bẹẹ maa n sẹ jalẹ oe kii ṣe iditẹgbajọba.

Ni ọdun 2017, iditẹgbajọba fopun si iṣejọba Robert Mugabe lẹyin ti ti lo ọdun mẹtadinlogoji nipo

Amọ ọkan lara awon ọgagun to dari iditẹgbajọba naa, Sibusiso Moyo bọ sori mohunmaworan kati kede oe kii ṣe iditẹgbajọba, igbajọba ologun ni

Loṣu kẹrin ọdun 2021 lẹyin iku aarẹ Chad nigba naa, Idriss Déby, awọn ologun fi ọmọ rẹ jẹ aarẹ fidihẹ lati darí ijọba fidihẹ.

Jonathan Powell so pe, “awon aditẹgbajọba kii yẹ sẹlori ipa ti wọn ba koninu iditẹgbajọba gẹgẹ bi ara ọna lati mu ki araye ri iditẹgbajọba wọn gẹgẹ bi eyi to tọna”

Bawo ni iditẹgbajọba ṣe n wọpọ si ni Afirika?

Nnkan bii ìṣẹlẹ iditẹgbajọba mẹrin lọdun la le fi iṣiro sí lọdun laarin ọdun 1960 si 2000.

Jonathan Powell ni eyi kii ṣe iyalẹnu pẹlu awọn hilahilo to waye lawọn orilẹede wọnyí lẹyin ti wọn ba gba ominira.

Lọdun 2000, iye iṣẹlẹ iditẹgbajọba to waye ni Afirika dinku gidigidi.

Laarin ọdun melo kan sẹyin ni gbọnmọgbọnmọ iditẹgbajọba tun bẹrẹ si nii yọju pada.

Aworan atọna nipa iditẹgbajọba

L’ọdun 2020 iṣẹlẹ iditẹgbajọba kan ṣoṣo lo waye, lorilẹede Mali si ni.

L’ọdun 2021, orilẹede marun un (Chad, Mali, Guinea, Sudan ati Niger ) ni iditẹgbajọba ti waye

L’ọdun 2022 igba marun un ọtọọtọ ni iditẹgbajọba waye, meji ninu wọn – lorilẹede Burkina Faso – lo kẹsẹjari.

Lorilẹede Sudan ni iditẹgbajọba ti wọpọ julọ. Igba mẹrindilogun ni iditẹgbajọba ti waye nibẹ, ṣugbọn mẹfa pere lo kẹsẹjari nibẹ.

L'ọdun 2019, awọn ologun yọ Omar al-Bashir kuro nipo lẹyin iwọde fun ọpọlọpọ oṣu.

Aworan awọn Ologun kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iditẹgbajọba lo gbe al-Bashir wọle sipo lọdun 1989.

Orilẹede Burkina Faso ni iditẹgbajọba ti kẹsẹhari julọ. igba mẹsan an ni iditẹgbajọba ti kẹsẹjari nibẹ, ẹyọ kan ṣoṣo lo foriṣanpọn.

Lorilẹede Naijiria ọpọ iditẹgbajọba waye lẹyin to gbominura. Mẹjọ ninu wọn lo waye laarin ọdun 1966 ati 1993 ti Ọgagun Sani Abach gba ijọba. Amọsa lati ọdun 1999 iṣejọba alagbada ti n lọ wọọrọwọ ni Naijiria.

Igba mọkanla ni iditẹgbajọba ti waye ni Burundi. Wahala laarin ẹya Tutsi ati Hutu lo si n fa eyi julọ.

Aworan atọna nipa iditẹgbajọba

Iditẹgbajọba mẹta lo ti waye ni Sierra Leone laarin ọdun 1967 si 1968, omiran lọdun 1971. Amọṣa laarin ọdun 1992 ati 1997, iditẹgbajọba marun un miran waye.

Lorilẹede Ghana, igba mẹjọ ọtọọtọ ni iditẹgbajọba waye nibẹ.

Akọkọ waye lọdun 1966, oun lo si gbe Jwane Njuruma kuru nipo.

Lodun 2021, akọwe agba ajọ iṣọkan agbaye, António Guterres sọ pe “ iditẹgbajọba awọn ologun tun ti pada de,”.

Lapapọ iditẹgbajọba wọpọ ni Afirika ju orilẹ miran lọ lagbaye. Ninu iditẹgbajọba mejidinlogun to waye lati odun 2017, ẹyọ kan ṣoṣo ninu wọn lo waye ni Myanmar, iyẹn lọdun 2021. Gbogbo iyoku, ilẹ Afirika ni wọn ti ṣẹlẹ.