Ààrẹ Gabon, Ali Bongo tí wà ní àhámọ́ àwọn ológun

Ali Bongo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ali Bongo, Aarẹ orilẹede Gabon ti awọn ologun yoo kuro jẹ ẹni ti o kọ iha ọtọọtọ si ọpọlọpọ.

Ṣi awọn kan, o jẹ ọmọ to bajẹ, elerepa ọmọọba to ri isakoso orilẹede Gabon gẹgẹ ẹtọ ibi rẹ, akọrin nigba kan ri to kẹsẹ bọ bata Baba lati tẹsiwaju bi mọlẹbi rẹ se n ṣe isakoso orilẹede naan fun ọdun mẹtalelaadọta.

Lọdọ awọn mii, o jẹ ẹni to fẹ mu ayipada ba ilu, eeyan to n wa ilọsiwaju ọrọ aje eyi ti yoo mu Gabon ba ẹgbẹ pe lawujọ.

Sugbọn iditẹgbajọba yii ṣi oju gbogbo agbaye si bi nnkan ṣe n lọ ni orilẹede naa si iye awon eeyan inu rẹ to miliọnu meji.

Awọn ologun ti bẹrẹ iwadi lori eto idibo to waye lọsẹ to kọja yi ti Ali Bongo bori gẹgẹ bi Aarẹ sugbọn ti alatako rẹ ṣi n lọgun pe wọn fi ọbẹ ẹyin jẹ oun ni iṣu ni.

Bayii, awọn olori ijọba ologun orilẹede naa sọ pe awọn ti fi Ali Bongo si ahamọ ni ile rẹ.

Ta ni Ali Bongo, ààrẹ Gabon tí àwọn ológun kéde pé àwọn ti gba ìjọba lọ́wọ́ rẹ̀?

Àkọlé fídíò, Gabon coup: Àwọn Ológun Gabon fi ìbínú sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí wọ́n fi já ìjọba gbà mọ́ ààrẹ wọ

Ní ọjọ́rú, ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Kẹjọ ọdún 2023 ni àwọn olọgun ní orílẹ̀ èdè Gabon kéde pé àwọn ti gbàjọba lọ́wọ́ ààrẹ orílẹ̀ èdè náà, Ali Bongo.

Ali Bongo ni àjọ alétò ìdìbò orílẹ̀ èdè náà ní ó jáwé olúborí fún sáà kẹta níbi ètò ìdìbò tó wáyé ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún ní ọjọ́ Àbámẹ́ta tó kọjá.

Ní ọdún 2009 ni Bongo di ààrẹ Gabon lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀ tó ló ọdún méjìlélógójì gẹ́gẹ́ bí ààrẹ orílẹ̀ èdè náà.

Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ali Bongo nìyí:

Alain Bernard Bongo ni àpèjá orúkọ rẹ̀ tí àwọn àbí rẹ̀ sọ, tí wọ́n sì bi ní ọjọ́ Kẹsàn-án oṣù Kejì ọdún 1959.

Òun ni ààrẹ kẹta tí yóò jẹ ní orílẹ̀ èdè Gabon, tó sì ti wà nípò náà látiọdún 2009.

Ọmọ ẹgbẹ́ Gabonese Democratic Party ni Ali Bongo.

Ó jẹ́ ọmọ bíbí Omar Bongo tó jẹ ààrẹ Gabon láti ọdún 1967 títí tó fi jáde láyé lọ́dún 2009.

Ali Bongo

Oríṣun àwòrán, Others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nígbà tí bàbá rẹ̀ wà nípò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Gabon, Ali Bongo Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè orílẹ̀ èdè náà láàárín ọdún 1989 sí 1991.

Lẹ́yìn náà ló lọ ṣojú Bongoville gẹ́gẹ́ bí igbákejì ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀ èdè náà láàárín ọdún 1991 sí 1999 kó tó tún di Mínísítà fétò ààbò láàárín ọdún 1999 sí 2009.

Lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ kú lọ́dún 2009, ó gbégbá láti díje dupò ààrẹ Gabon tó sì gbégbá orókè.

Ní ọdún 2016 ni wọ́n tún dìbò yan Bongo fún sáà kejì ṣùgbọ́n àwọn ẹgbẹ́ alátakò ní ètò ìdìbò náà kò gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀ àti pé títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lọjú mọ́lẹ̀ kún ètò ìdìbò náà fọ́fọ́.

Èsì ìdìbò náà kò tẹ́ àwọn kan lọ́rùn tí àwọn ológun sì gbèrò láti gba ìjọba nígbà àmọ́ tí kò bọ́ si.

Àjọ elétò ìdìbò tún kéde pé Bongo ló jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò ọdún 2023 báyìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹgbẹ́ alátakò tún fẹ̀sùn kàn pé àwọn àìṣedédé kan tún wáyé lásìkò ìdìbò náà.

Àwọn olọgun tó dìde láti gbàjọba kéde lórí amóhùnmáwòrán lọ́jọ́rú pé àwọn ti gbàjọba lọ́wọ́ Bongo, tí àwọn sì ti òpin sí ìṣèjọba rẹ̀.

Ní ilé ẹ̀kọ́ aládàáni kan ni Bongo ti kàwé ní Neuilly, orílẹ̀ èdè France , kó tó tẹ̀síwájú lọ sí Sorbonne láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin.

Ọdún 2018 ni wọ́n fi oyè ọ̀mọ̀wé da lọ́lá ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Wuhan, orílẹ̀ èdè China.

Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìms òfin rẹ̀ ló darapọ̀ mọ́ òṣèlú, tó sì darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Gabonese Democratic Party.

Ali Bongo gbé àwo orin jáde lọ́dún 1977 tó pe àkọ́lé rẹ̀ ní “A Brand New Man” èyí tó túmọ̀ sí “Ọkùnrin tuntun” tí Charles Bobbit ṣe olóòtú rẹ̀.

Ọmọ mẹ́rin ni Ali Bongo bí ọkùnrin mẹ́ta àti obìnrin kan.

Àwọn ológun kéde pé àwọn ti gbàjọba ní Gabon

Ali Bongo

Oríṣun àwòrán, AFP

Àwọn ọmọ ní Gabon tí bọ sórí ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán pé àwọn ti gbàjọba orílẹ̀ èdè náà.

Wọ́n ní àwọn wọ́gilé èsì ìdìbò tó wáyé ní orílẹ̀ èdè náà lópin ọ̀sẹ̀ níbi tí wọ́n ti kéde Ààrẹ orílẹ̀ èdè ọ̀hún Ali Bongo pé òun ló jáwé olúborí.

Àjọ elétò ìdìbò orílẹ̀ èdè Gabon ní Bongo ló jáwé olúborí nínú ó dín díẹ̀ nínú ìdá méjì gbogbo ìdìbò tí wọ́n dì níbi ètò ìdìbò náà.

Ìdìtẹ̀gbàjọba yìí ni yóò fi òpin sí ọdún mẹ́tàléláàdọ́ta tí ẹbí Ali Bongo ti ń jẹ Ààrẹ Gabon.

Àwọn ọmọ ogún bíi méjìlá ló kó ara wọn jọ sórí amóhùnmáwòrán lọ́jọ́rú láti kéde pé àwọn ti wọ́gilé èsì ìdìbò náà àti pé gbogbo àwọn iléeṣẹ́ tó jẹ́ ti orílẹ̀ èdè náà ni àwọn ti fòfin dè.

Bákan náà ni wọ́n sọ wí pé gbogbo ẹnubodè tó wọ orílẹ̀ èdè ọ̀hún ni àwọn ti tì pa títí di ìgbà kan ná.

Tí ìdìtẹ̀gbàjọba yìí bá filè kẹ́sẹ járí, òhun ló máa jẹ́ ìdìtẹ̀gbàjọba kẹjọ tí yóò wáyé nílẹ̀ Adúláwọ̀ ní àwọn orílẹ̀ èdè tí ìjọba ilẹ̀ Faransé kó lẹ́rú.

Àwọn ológun náà ní àwọn wà lára ìgbìmọ̀ kan tó wà fún àtúntò orílẹ̀ èdè náà àti pé àwọn jẹ́ aṣojú àwọn ọmọ ogún orílẹ̀ èdè náà.

Ọ̀kan nínú àwọn ológun náà ní àwọn dìde láti dá ààbò bo àláfíà orílẹ̀ èdè Gabon nípa fífi òpin sí ìṣèjọba tó wà lóde èyí tó ti ń wakọ̀ orílẹ̀ èdè náà lọ sí oko ìparun.

Lẹ́yìn ìkéde yìí ni ìró ìbọn ń dún lákọlákọ ní olú ìlú orílẹ̀ èdè náà, Libreville.

Olóòtú ikọ̀ ìròyìn BBC World Service Africa, Will Ross sọ wí pé èyí túmọ̀ sí pé ìdìtẹ̀gbàjọba náà kò ì tíì kẹ́sẹ járí, tí ààrẹ orílẹ̀ èdè náà sì má fẹ̀ ẹ́ jẹ́ kó wáyé.

Ìjọba kò ì tíì fèsì tàbí sọ ohunkóhun sí ìkéde àwọn ológun yìí, tí a kò sì nímọ̀ nípa ibi tí ààrẹ Bongo wà báyìí.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń wáyé ní Gabon, àwọn ìkọnilọminú wà lórí ètò ìdìbò tó wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Alátakò gbòógì tó bá Bongo du ipò ààrẹ náà, Albert Ondo Ossa fẹ̀sùn kan pé ọ̀pọ̀ àwọn ibùdó ìdìbò ni kò sí orúkọ òun lórí ìwé ìdìbò àti pé ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti kéde pé àwọn kò díje mọ́ ni orúkọ wọn ṣì wà lórí ìwé ìdìbò.

Ní ọdún 2009 ni Bongo di ààrẹ Gabon lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ tó wà lórí ipò náà tẹ́lẹ̀ jáde láyé.

Nígbà tí àìsàn kan da gúnlẹ̀ fún bí ọdún kan lọ́dún 2018 ni ọ̀pọ̀ ènìyàn ní kó yẹ̀bá lórí ipò náà ṣùgbọ́n tó tẹ̀síwájú lórí ipò náà.

Ní ọdún tó tẹ̀le ní wọ́n gbèrò láti dìtẹ̀gbàjọba lọ́wọ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò jẹ́ àṣeyọrí tí wọ́n sì rán àwọn ológun tó gbèrò rẹ̀ lọ sẹ́wọ̀n.