Ológun kò ní gbàjọba ní Naijiria, ẹ̀yin ọlọ́tẹ̀ ẹ gbẹ́nu dákẹ́ - Iléeṣẹ́ Ọmọogun Naijiria

Aworan

Oríṣun àwòrán, Nigerian Defence

Ikọ ọmọogun lorilẹede Naijiria ti fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe ijọba ologun ko ni waye ni Naijiria.

Ileeṣẹ ọmọogun Naijiria sọ eyi lati tako iroyin to n kaakiri to n kesi awọn ikọ ọmọogun Naijiria lati gba ijọba ni tipatipa.

Wọn ṣe apejuwe awọn to n pe fun ijọba ologun gẹgẹ bi awọn ọbayejẹ ati ika eniyan.

‘’Ileeṣẹ ikọ ọmọogun Naijiria ko dunnu si awọn eniyan to n pe loju ẹrọ ayelujara fun awọn ikọ ọmọogun lati gbajọba nitori wọn ko tọju wọn.

Ninu atẹjade ti Ọgagun Tukur Gusau gbe jade ni wọn ti fi aidunnu wọn han si awọn araalu.

‘’A ri pe nigba gbọgbọ ni awọn ọmọogun wa wa ni alaafia , ti a si n tọju wọn bi o ṣe tọ ati bi o ṣe yẹ, amọ ko dara to bi awọn ọbayejẹ kan ṣe n pe fun awọn ologun lati doju ijọba tiwantiwa bolẹ ni Naijiria’’

''A fẹ ki awọn araalu mọ pe ijọba Naijiria tẹ wa lọrun , a ko si ṣetan lati doju ijọba tabi ofin Niajiria bolẹ.''

''Ijọba tiwantiwa to bẹru fun ofin ni a fẹ, ti a si fẹ ṣiṣẹ labẹ rẹ.''

Laipẹ yii ni awọn ologun gbajọba ni Niger, ti eyi si jẹ ẹlẹkẹẹsan ti yoo waye ni iwọ oorun ilẹ Afrika.

Awọn orilẹede ti ologun ti gbajọba bẹrẹ lati ọdun 2020 ni Mali, Guinea, Burkina, to fi mọ Chad.

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu to jẹ adari ajọ ECOWAS lo n dari igbiyanju lati da ijọba tiwantiwa pada si Niger.