'Wọn kò tíì san owó tí ìyà Boluwatife yá lórí ẹ̀kọ́ ọmọ rẹ̀ padà, tí wọn fi pa ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ jáde'

Boluwatife

Oríṣun àwòrán, Tijani Oluṣegun

BBC Yoruba ṣe abẹwo si agbegbe 'Ifẹlodun zone 3 Iwo Road' Mọlade Ibadan nibi ti akẹkọọ fasiti Lead City ti awọn olubi ẹda kan ṣekupa, Omoniyi Boluwatife gbe pẹlu iya rẹ.

Ilẹkun ile naa wa ni titi pa, ṣugbọn awọn aladugbo ati ọkan ninu awọn ọrẹ oloogbe ṣe alaye fun akọroyin wa pe ile iwosan kan ni wọn sare gbe iya oloogbe lọ nipasẹ ijaya to ni lẹyin ti wọn tufọ iku ọmọ rẹ fun un.

Ọkan lara awọn ọrẹ Boluwatifẹ ti o tun jẹ ọmọ ile ijọsin kan naa pẹlu rẹ, Tijani Oluṣegun ṣe alaye wi pe ọsẹ to kọja ni Boluwatifẹ kẹkọọ gboye Nọọsi ni fasiti Lead City nilu Ibadan, bẹẹ sini o ṣe idupẹ ni Ṣọọṣi ti wọn jọ n lọ.

Tijani Olusegun

O ni nnkan iyalẹnu lo jẹ bi oun ṣe dede ri iroyin lori ayelujara wi pe wọn pa Boluwatifẹ lẹyin ti wọn kuro nibi ile ijo kan ti wọn ti lọ ṣe ayẹyẹ ikẹkọọjade, ti awọn olubi ẹda naa si yọ ile ọmọ rẹ lọ.

Tijani ṣe alaye pe nnkan ibanujẹ ni iṣẹlẹ naa nitori ẹnikẹni ko ni ero iru iṣẹlẹ bẹẹ si Boluwatifẹ.

O ke si ijọba ati awọn agbofinro lati gbe igbesẹ ti o yẹ lati fi oju awọn olubi ẹda naa han.

Ilé àwọn Boluwatife
Mutiat Yahaya

Arabinrin Mutiat Yahaya to n gbe ni ẹgbẹ ile awọn Boluwatifẹ ṣe alaye pe awọn obi ọmọ naa ti jiṣẹ-jiya ju nitori ki awọn ọmọ wọn le de ibi giga laye.

O ni, "Mo bẹ gbogbo ọmọ Naijiria, gbogbo abiyamọ aye, iya yii ko gbọdọ jẹ iya yii gbe, nitori wahala ti iya ati baba ṣe lori ọmọ yii... Wọn ko ni nnkan kan Ṣebi ẹyin naa ri ibi ti wọn n gbe.

Wọn ko ni nnkan kan ṣugbọn latari pe ki ọjọ ọla wọn le daa ni wọn ṣe ni ki Bolu lọ si ibi to lọ."

Mutiat ni iya Boluwatifẹ ko tii ri owo ti o ya lati ran Bolu lọ si ile ẹkọ san pada ti iṣẹlẹ aburu naa fi ṣẹ.

O pe fun idajọ ododo lori awọn ika eniyan ti wọn fi ọmọ da iya Boluwatifẹ loro.

Awọn ara adugbo ile Boluwatife

Ẹni ti o jẹ akọwe adugbo naa, Alhaji Yẹkini Alausa ṣe alaye wi pe ọmọ daadaa ni wọn mọ Boluwatifẹ si ni adugbo, nitori jẹjẹ rẹ lo maa n lọ.

O ni lojiji ni awọn gbọ iroyin wi pe "wọn ti da emi Boluwatifẹ legbodo, wọn si ju oku rẹ si agbegbe Dandaru ni ọna Mọkọla."

Alausa fi idi ọrọ mulẹ wi pe Boluwatifẹ ati iya rẹ ni wọn jọ n gbe ile naa ni gbogbo igba ti o ba wale lati ile ẹkọ giga ti o wa.

O ni orilẹede South Africa ni baba Boluwatifẹ fi ṣe ibugbe, ẹkọọkan lo si maa n bẹ wọn wo.

Alausa ni idajọ ododo ni ẹbi oloogbe naa nilo lori ọrọ iku ọmọ naa, nitori awọn eeyan kan lo da ẹmi rẹ legbodo.

A kan si ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lati mọ ibi ti wọn ba iṣẹ de lori ọrọ naa. Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Adewale Ọṣifẹṣọ ṣe alaye wi pe ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn afurasi kan, ṣugbọn iṣẹ iwadii n lọ lọwọ.

Taa ló pa Boluwatife tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Nọ́ọ̀sì, tó tún yọ nǹkan lọ lára rẹ n'Ibadan?

Boluwatife ati iya rẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Wọn ti ri oku ọdọmọbinrin kan, Omoniyi Boluwatife, akẹkọjade ni Lead City University, lẹgbẹ ọna niluu Ibadan.

Iroyin sọ pe wọn ri oku rẹ lẹyin to lọ si ibi ayẹyẹ kan lati ṣe ajọyọ didi akọṣẹmọṣẹ nọọsi.

Ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹjọ ni wọn ri oku Boluwatife, ti awọn ẹ̀yà ara rẹ kan ti di awati.

Ninu fidio kan to n lọ kaakiri lori ayelujara, o han pe wọn la ikùn rẹ ki wọn to yọ awọn ẹya ara rẹ kan lọ, ti wọn si fi aṣọ bo o pada.

Awọn iroyin kan sọ pe ile ọmọ to wa ninu rẹ ni wọn yọ, àmọ́ a ko le fidi eyi mulẹ.

Wọ́n ṣẹṣẹ gba Boluwatife wọle sinu ẹgbẹ́ awọn nọọsi ati agbẹbi ni orile-ede Naijiria ni, ti iya ati awọn ọrẹ rẹ naa si wa lati ba a ṣe ayẹyẹ.

Lẹyin eto iburawọle ni Boluwatife lọ fun ajọyọ miran nile faaji kan, Nightclub, niluu Ibadan.

Ile faaji ni àwọn o mọ nkankan nipa iku rẹ

Lẹyin ti iroyin iku Boluwatife jade sori ayelujara, ni àwọn ọmọ Naijiria ti n kesi ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe iwadii.

Sugbọn botilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa, awọn alaṣẹ ile faaji ti ọmọbìnrin naa lọ, ti sọrọ.

Copacapana sọ nínú atẹjade kan pe awọn o le gba ẹbi iṣẹlẹ naa, nitori pe kii ṣe ọdọ wọn lo ti sẹlẹ.

Ẹnikan lara àwọn aláṣẹ wọn to ba BBC Pidgin sọrọ, ní oriṣiriṣi eeyan lo ma n wa si ile faaji naa - ohun to ba sẹlẹ si wọn lẹyin ti wọn kuro nibẹ ko kan ile faaji naa.

"Àwọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, iranlọwọ nnkan ti ẹ̀rọ ayaworan CCTV wa ká silẹ nikan si la le ṣe fun wọn nitori pe kii ṣe sàkání wa lo ti sẹlẹ."

Ile faaji naa sọ pe awọn yoo fun awọn ọlọpaa ni gbogbo nǹkan to le tọka si ẹni to wa pẹlu Boluwatife ni alẹ́ ọjọ to lọ sile faaji naa.

Iru iṣẹlẹ yii waye laipẹ niluu Ibadan

Oṣù diẹ ṣeyin ni iṣẹlẹ to jọ eleyi waye niluu Ibadan, lasiko ti wọn ba oku ọmọbìnrin kan ninu yara ile itura.

Arabinrin Olayinka Adesina, to jẹ ilumọọka alaṣọ lori ayelujarna ti wọn tun mọ si Khadi, ni wọn ba oku rẹ ninu ile itura kan ni agbegbe Akobo, ni ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo, lọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, 2023.

Olayinka, ti o gbajugbaja fun awọn aṣọ alaranbara to ma n ran ati baagi to ma n ta lori ẹrọ ayelujara, ni wọn ni o sọ fun ọrẹ rẹ kan pe oun fẹ lọ pade ẹnikan ni ile itura kan.

Ọkunrin naa lo ji kuro ni ile itura naa ni ọjọ keji amọ ti wọn si pe yara ti Khadi wa, to si sọ fun oṣiṣẹ ile itura naa pe alaafia ni oun wa, ki wọn to gba ki ọkunrin naa maa lọ.

Amọ, oku Khadi ni wọn ba lẹyin ọpọ wakati to ti yẹ ko jade, ti wọn ko si gburo rẹ tabi ko gbe ipe rẹ.

Iroyin bi ọkùnrin ti oun ati Olayinka jọ sun nile itura ṣe fa ara rẹ le ọlọpaa lọwọ la gbọ kẹhin. Ileeṣẹ ọlọpaa ko tii pada sọrọ lori ibi ti iwadii wọn de.