Ilé Òòṣà ni àfin ọba nílẹ̀ Yorùbá, kìí ṣe ṣọ́ọ̀ṣì tàbí mọ́ṣáláṣí, kí Ọba tó bá fẹ́ pa ìṣẹ̀ṣe rẹ́ jìnà sí àfin -Àwọn oníṣẹ̀ṣe

Àkọlé fídíò, Awọn oniṣẹṣe naa sọ pe ni ilẹ Yoruba, olu ibudo ẹsin iṣẹṣe lo ni aafin Ọba.

O ti n to ọjọ mẹta bayii ti ọrọ ati iṣesi awọn lọbalọba lori aleefa, paapaajulọ nipa iṣẹṣe ti n ja ranyinranyin.

Pupọ awọn ọba ni ilẹ Yoruba bayii ni wọn kii fẹ lwọ si iṣẹṣẹ mọ lẹyin ti wọn ba de ori apere.

Ọpọ miran a tilẹ b si gbangba lati kede pe awọn ko si fun iṣẹṣe mọ, ti awọn kan yoo tilẹ maa pariwo pe ko si ohun to n jẹ oriṣa tabi ẹsin abalaye mọ paapaa lori ọrọ oye jijẹ.

Ile oriṣa ni afin gbogbo ni ilẹ Yoruba -Awọn oniṣẹṣe

Ifaṣọla Ọpẹodu, alakoso ẹgbẹ oniṣẹṣe ni ipinlẹ Ogun

Awọn oniṣẹṣe to ba BBC News Yoruba sọrọ pẹlu ti koro oju si eyi paapaa pẹlu ofin ti ijọba ipinlẹ Ogun ṣe nipa isinku awọn ọba ni ipinlẹ naa.

Wọn ni iwa ti ko bojumu lawọn ọba ti ọrọ kan yii gbe si ọwọ nitori pe wọn mọ pe iṣẹṣe lo wa ni idi ọrọ oye jijẹ nilẹ Yoruba ki wọn to tẹri sii.

"Iwọ to ba jẹ Kristẹni, tabi Musulumi, ọjọ to ba ti mọ pe o n lọ si ipo ọba, o ti mọ pe o n lọ dara pọ mọ oniṣẹṣe niyẹn."

Wọn fi kun un pe ni ilẹ Yoruba, olu ibudo ẹsin iṣẹṣe ni aafin jẹ kii ṣe mọṣalaṣi tabi ṣọọṣi.

Wọn ni ẹni to ba ri pe ohun ti wọn n ṣe ko tẹ oun lọrun ko jinna si ipo ọba.

Ébi ọba kii pa eeyan, ko si ibi ti wọn ti n ge ori ọba nilẹ Yoruba'

Ifaniyi Awoniyi to jẹ akọwe ajọ awọn oniṣẹṣe ni ipinlẹ Ogun

Bakan naa lawọn oniṣẹṣe to sọr naa ṣalaye pe ko si ibi ti wọn ti n sinku ọba ti wọn ti n ge ori tabi ẹya ara kankan.

Alagba Ifaṣọla Ọpẹodu, alakoso ẹgbẹ oniṣẹṣe ni ipinlẹ Ogun ṣalaye pe ko si ẹni to le fi idi rẹ mulẹ pe ko si ibi kankan ti wọn ti n pin ẹya ara ọba kankan bi wọn ba pa ipoda.

O ni aimọkan lo n da awọn eeyan atawọn ọbalaye kan to n sọ ọ kaakiri pe 'wọn n da ina ya ọba' tabi pe wọn n ge ori ati ẹsẹ ọba lati ri mọ'lẹ kaakiri ilu.

O wa fi ipenija sita si awọn ọba to n sọrọ yii pe bi wọn ba ti ri iru rẹ ri, ki wọn bọ sita wa sọ.

Ko si aigbọraẹniye laarin ilana isinku iṣẹmbaye ati ofin tuntun ti ijọba ogun gbe jade

Awọn ẹlẹsin ibilẹ lasiko ọdun Ọṣun Oṣogbo

Wọn ni gbogbo igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Ogun gbe nipa ofin ti wọn gbe kalẹ lori isinku ọba ni ipinlẹ naa.

Ifaniyi Awoniyi to jẹ akọwe ajọ awọn oniṣẹṣe ni ipinlẹ Ogun ṣalaye pe ko si atako kankan laarin ilana isinku ọba ati ofin tuntun ti ijọba ipinlẹ ogun ṣẹṣẹ gbe kalẹ.