Ààrẹ Ọ̀nàkakaǹfò gbanájẹ, Ó ní kí ìjọba Kwara ó kìlọ̀ fáwọn alákatakítí ẹ̀sìn Islam tó fẹ́ d’ógun ẹ̀sìn sílẹ̀ ní Ilorin

Oríṣun àwòrán, Instagram/Aare Gani Adams
Aarẹ ọna kankanfo gbogbo Yoruba, Iba Gani Adams ti kọwe ranse si Gomina Ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRasaq lati tete wa nnkan ṣe si awọn alakatakiti ẹsin ti wọn n dun mọhurumọhuru mọ awọn ẹlẹsin ibilẹ nipinlẹ Kwara paapaajulọ ni ilu Ilọrin.
Aarẹ ni gbogbo aye lo mọ ipinlẹ Kwara gẹgẹ bi ilu alaafia, ti gbogbo ẹsin to wa labẹ ofin paapa ẹsin Kristẹni, Islam ati Onisẹse ni wọn se nibẹ.
Lẹnu lọwọlọwọ yii ni gun-gun-gun bẹrẹ si ni waye laarin awọn alaafa kan ati iya ẹlẹsin ibilẹ to n bọiyemọja lagbegbe kan nibẹ.
Ohun ti awọn afaa naa n sọ ni pe Ilu Musulumi ni ilu Ilọrin ti wọn si n leri leka pe bi wọn ba kẹfin oniṣẹṣe kankan to n ṣọdun iṣẹsẹ nib, awọn yoo ba a wọ ṣokoto kan naa.
Eyi ti mu ki okayasoke o wa nigboro pẹlu bi ayẹyẹ ajọdun iṣẹṣe ti yoo waye ni ogunjọ oṣu kẹjọ ọdun 2023 ṣe n sunmọ etile.
"Lati bi irinwo ọdun sẹyin ni gbogbo awọn ẹsin yii ti jọ gbe papọ niluu Ilorin.
"Ilẹ Yoruba ni Ilorin jẹ to si jẹ pupọ awọn eeyan to wa nibẹ lo jẹ Musulumi sugbọn a si ni awọn Kristẹni ati Onisẹse to wa ninuu Ilorin, ti wọn si n sin Ọlọrun wọn.
Ẹ ke si Emir Ilorin ko kiyesara nipa awọn to n fi orukọ rẹ huwa ẹlẹsinjẹsin ni Ilọrin - Gani Adams
Iba Gani Adams tẹsiwaju pe ki gomina ipinlẹ Kwaratete kọ si Emir ti ilu Ilorin, Ibrahim Kolapo Sulu Gambari lati da awọn to n fi orukọ rẹ sọ wahala ẹsin ti wọn n da silẹ
Aarẹ ni bi awọn Musulumi kan se gbegi dina fun Iya Osun kan to fẹ ṣe ọdun ọṣun rẹ niluu Ilorin ku diẹ kaa to, to si lee fa ija ẹsin.
“Mo fẹ fi to awọn alakatakiti ẹsin wọnyi leti pe ibọwọ fun ofin wa jakejado Naijiria, titi kan ilu Ilọrin, ko si tọna fun ẹnikẹni lati wa bẹrẹ ilana ibọwọ fun ifẹ ara ti wọn.”
Ko si ẹni to lẹtọ lati ja fun Ọlọrun
Aarẹ Gani Adams ni o sese ki gbogbo araalu mọ pe Ọlọrun ti ẹsin Kristẹni, Islam ati Onisẹse n sin ki se Ọlọrun to madaru tabi janduku tabi okunkun sugbọn Ọlọrun to fẹ ki a fi aye gba biba ara wa gbe pẹlu imọlẹ.
"A ko fẹ ki nnkan to waye ni Sokoto nigba ti awọn eeyan kan sekupa Deborah nitori ẹsin waye niluu Ilorin.
"N ko mọ bi ọdun yii se fẹ se akoba fun Kristẹni to wa ninu Sọọsi to n gba adura tabi Musulumi to n gba adura ni Mọsalaasi.
"Ni Israel ati Saudi Arabia, awọn olori ko fi aye silẹ ki ẹsin se akoba fun ilọsiwaju imọ ẹrọ wọn."
Kii se awọn Musulumi lo nilo idabo bo gomina, gbogbo ẹlẹsin ni - Iba Gani Adams
Iba Gani ni ọpọ eeyan lo ti sọ pe nitori Gomina jẹ Musulumi ni aye fi gba awọn Musulumi nipinlẹ Kwara lati ma dunkoko mọ awọn ẹlẹsin yooku.
O wa rọ Gomina lati tẹle ibura to se lasiko ti wọn bura fun gẹgẹ bi Gomina lọdun 2019 ati 2023 pe oun yoo dabo bo gbogbo ara ipinlẹ Kwara.
"N ko fẹ gbagbọ ninu nnkan ti awọn eeyan kan sọ pe nitori Gomina jẹ Musulumi ni awọn awọn Musulumi fi n tako awọn ẹlẹsin yooku.
"Eyi ko ni itẹwọgba, a ko gbọdọ fun awọn eeyan yii laye lati sọ ilu Ilorin di itan gbangba fun ogun ẹlẹsin de."
A ko ti ri lẹta ti Aarẹ Gani Adams Kọ ransẹ- Agbẹnusọ Gomina Ipinlẹ Kwara
Ileeṣẹ BBC Yoruba kan si Agbẹnusọ Gomina ipinlẹ, Rafiu Ajakaye lati sọrọ lori lẹta si Aarẹ Gani kọ arnsẹ si Gomina AbdulRahman AbdulRasaq.
Ajakaye ni oun ko ti ri lẹta ọhun, ti oun ko si le sọ nkankan lori rẹ.
Ki ni ileeṣẹ Ọlọpaa sọ?
Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Kwara ni oun naa ko ti ri lẹta ti Iba Gani Adams kọ si Gomina lori ede aiyede to waye laarin awọn Onisẹse ati awọn Musulumi sugbọn gbogbo igbesẹ ni awọn ti gbe lati ma ji wahala bẹ silẹ lasiko Ọdun Isẹse.
Agbẹnusọ Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ajayi Okesanmi ni gbogbo nnkan to yẹ ki Ọlọpaa n se lati ri pe ko si ede ayede laarin awọn ẹlẹsin naa mọ.
"Laipẹ yii, a mọ pe awọ wa laarin awọn Onisẹse ati awọn Musulumi, Kọmisọna pe wọn , o si ba awọn mejeeji sọrọ, ti wọn si ti tọwọ bọ iwe pe ko ni si wahala."
"Lati ọjọ yẹn, ko wahala mọ. Fun ti Ọdun Isẹse, awọn Ọlọpaa wa nilẹ lati ri pe ko si wahala kankan nipinlẹ Kwara."















