Ẹ kópa nínú òṣèlú láti ṣe àfọ̀mọ́ ìdìbò Nàìjíríà - Obasanjo kesi àwọn Kírísítẹ́nì

Oríṣun àwòrán, Google
Aarẹ Naijiria tẹlẹ Olusegun Obasanjo ti rọ awọn ọmọ lẹhin Kristi lati kopa ninu eto oṣelu lọna ati dẹkùn iwa ibajẹ ninu idibo Naijiria.
O fìdí ọrọ yí múlẹ lasiko to n kópa ninu eto ijọsin ìjọ Godpel Faith Mission International lọjọ Àbámẹ́ta.
Aarẹ tẹlẹ yi sọ pé lasiko yi to ṣe pe aabo mẹhẹ,ti iporuru ọkan ati iṣẹ gbode ile ijọsin ni lati gberasọ lati lè jẹ iyọ ninu igbesi araalu
O ni "iwa magomago ti f'ẹsẹ rinlẹ gẹgẹ bi ọpọ to di ìdìbò Naijiria mu.Eeyan kò sí le fi iwa ibajẹ se ìpìlẹ nkan ki kíni naa lojutu"
O tọka sí idibo ọdún 1999 to sì ni iriri buruku toun ti nipa idibo nigba ti ìdìbò ijọba ibilẹ waye ti awọn èèyàn di tako ẹgbẹ oṣelu PDP.
Obasanjo loun ko fún wọn ní owo kankan nitori oun ro pe o yẹ ki gbogbo awọn wọnyi ti gba owo lọdọ ileeṣẹ ìjọba ti o gba wọn ṣiṣẹ.
O tẹsiwaju pe nigba ti jẹ iṣẹ ti wọn n gba owo oṣù le lori ko yẹ lóun fún wọn ní owo kankan .
O ní aifunwọn lowo yi wa lara nkan ti PDP fi fidirẹmi ninu idibo ijọba ibilẹ.
O wá rọ awọn ọmọ ile ijọsin lati yago fun iwa ajebanu ki wọn sì f'ọkan sí kikopa ninu idibo lati lè mu iyipada ba oṣelu Naijiria.















