Trinity Guy tẹ̀wọ̀n dé, ó di oníle tuntun

Oríṣun àwòrán, Trinity guy/instagram
Gbajúmọ̀ apanilẹ́ẹ̀rín, Abdullahi Maruf Adisa tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Trinity Guy ti di onílé tuntun.
Ori ayelujara Instagram rẹ ni Trinity guy ti kéde àṣeyọrí ilé nàá ní Ọjọ́bọ̀.
Nínú ọ̀rọ̀ tó kọ sí abẹ́ àwọn àwòrán tó fi síta, Trinity Guy sọ pé òun fi ilé nàá ṣe ẹ̀bùn fún ara òun, lẹ́yìn tí òun la oríṣiríṣi kọjá.
Ó ní “mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Allah, àwọn olólùfẹ́ mi káàkiri àgbáyé, àti sí ẹbí mi...”
Ìkéde ilé tuntun nàá n wáyé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí Trinity Guy jáde kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣu Keje, ni Trinity Guy gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Bi ẹkun pẹ titi di alẹ fun Trinity Guy, ayọ de fun ni owurọ
Ẹ ó rántí pé láti ọjọ́ Kejìlélógún oṣù Kẹfà ọdún 2023 tí Trinity Guy ti fojú bá ilé ẹjọ́ lórí fídíò kan tó ṣe tí ọmọdé wà níbẹ̀.
Nínú fídíò náà ni Trinity Guy ti ń bèèrè àwọn ọ̀rọ̀ àlùfàǹṣá lọ́wọ́ ọmọ náà tí èyí sì fà awuyewuye lórí ayélujára.
Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá sọ pé ìwà nàá jẹ́ líló ọmọdé ní ọ̀nà àìtọ́.
Ní ọjọ́ náà ni ilé ẹjọ́ Májísíréètì tó wà ní Iyaganku, Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo ní kí wọ́n fi Trinity Guy sí ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di oṣù Kẹjọ.
Yàtọ̀ sí Trinity Guy, ilé ẹjọ́ tún fi àwọn òbí ọmọ náà sí àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n pé àwọn náà lọ́wọ́ nínú fídíò tí Trinity Guy ṣe.

Oríṣun àwòrán, Trinity Guy
Ta a ni Trinity Guy?
Bẹ̀rẹ̀ sí lo orúkọ́ nàá tó túmọ̀ sí mẹ́talọ́kan, nítorí pé ìbẹta ni.
Ṣáàjú kọ tó di apanilẹ́ẹ̀rín, Trinity Guy ti ṣiṣẹ́ rí gẹ́gẹ́ bí alámójúto odò ìwẹ̀ ìgbàlódé ‘swimming pool’, àti olùkọ́ eré ìdárayá.
Ó sọ èyí di mímọ̀ nínú ìfọrọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú BBC Yoruba lọ́dún 2023.













